Ipo aarẹ ko tọ sẹnikẹni to ba ti ju aadọrin ọdun lọ ni Naijiria – Ortom

Gbenga Amos

“Ẹ wo awọn eeyan atata mẹta yii, ẹ wo wọn kẹ ẹ tun wọn wo, ṣe ẹ le fi wọn we awọn arugbo kujọkujọ ti wọn lawọn fẹẹ di aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, pẹlu ba a ṣe wa laye ọlaju yii. Ẹ jẹ ka fawọn ọdọ laaye. Mo ranti ọrọ ti gomina ẹlẹgbẹ mi kan sọ, mo si kin in lẹyin, ẹnikẹni to ba ti ju ọmọ aadọrin ọdun lọ, to tun loun fẹẹ dupo aarẹ, olubi eeyan to fẹẹ doju orileede yii de ni, ko jawọ nbẹ.”

Ọrọ kanka ti Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, fọ mọlẹ ree, lasiko tawọn agbaagba ẹgbẹ PDP kan ṣabẹwo si i nile ijọba ipinlẹ Benue, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii. Awọn mẹta ọhun ni gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Bukọla Saraki, gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ati tipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed.

Awọn mẹta yii lawọn waa ba Samuel Ortom fikun lukun lori ero ati aba wọn nipa eto yiyan ondije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti gbogbo wọn wa, ati idi to fi maa daa ki ẹgbẹ naa lo ilana afẹnuko-yan ti wọn n pe ni kọnsẹsọọsi (concensus) lede eebo, dipo ilana idibo gbangba-laṣa-i-ta.

Ninu ọrọ rẹ, Ortom gboṣuba fawọn alejo rẹ yii, o ni:

“Awọn ọmọ Naijiria naa le jẹrii si i pe awọn eeyan yii peregede, wọn fi gbọọrọ jẹka, wọn si to tan lati di olori orileede yii, tori lasiko ti wọn fi wa nipo ninu ijọba apapọ, wọn fakọ yọ lori iṣẹ ta a ran wọn.

Igbesẹ ti wọn si gbe yii, nnkan daadaa ni, igbesẹ iṣọkan ni, oṣuṣu ọwọ lo ṣe e gbalẹ mọ.

“Mo rọ wọn lati tẹsiwaju ninu ifikunlukun ati ifimọṣọkan wọn, laarin ara wọn atawọn mi-in pẹlu. Wọn ti sọ pe awọn maa ṣabẹwo sawọn agbegbe yooku, titi kan iha Guusu ilẹ wa, ki wọn le lajọsọ pẹlu awọn to fẹẹ dupo aarẹ lapa ibẹ.

“Ẹ jẹ ka jọ ṣiṣẹ papọ. Pẹlu bi PDP ṣe jẹ alatako loni-in, awa lẹgbẹ to n ṣakoso lọwọ n wo niwaju, idi si niyẹn ti PDP fi fẹẹ gba akoso ka le doola ẹmi Naijiria, ka si tun un ṣe. Ana ode yii ni ẹni iyi kan lati ipinlẹ Rivers, Gomina Wike, ṣabẹwo, to si kede pe oun fẹẹ dupo aarẹ.”

Saraki, to ti figba kan jẹ olori awọn aṣofin apapọ lo sọrọ lori ete abẹwo wọn, o ni:

“Idi ta a fi wa sibi lonii da lori erongba awa mẹtẹẹta yii ta a ti pinnu lati jade dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ wa (PDP). Lati ọsẹ diẹ sẹyin la ti n ba ara wa sọrọ, ta a si n ronu lori ọna ti ẹgbẹ wa yoo fi mu ọmooye kan ti gbogbo wa maa fẹnuko-yan jade, tori ohun to maa ṣe Naijiria loore lo ṣe pataki ju anfaani tẹnikọọkan fẹẹ ri, lọ. Ko sẹni ti ko kunju oṣuwọn lati ṣe olori laarin wa, ṣugbọn ti Naijiria lo ja ju, ti ẹgbẹ wa si ṣe koko pẹlu.”

Leave a Reply