Ipo Aarẹ ti mo fẹẹ du yii, lati kekere ni mo ti ni in lọkan – Tunde Bakare

Olori ile ijọsin The Citadel Global Community to wa niluu Eko, Pasitọ Tunde Bakare, ti sọ pe lati kekere loun ti ni in lọkan lati di aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọjọ kan, bo tilẹ jẹ pe oun ko si ninu awọn to fẹẹ fi tipatipa wa a.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ọkan pataki ninu awọn oniroyin ni Naijiria lori instagiraamu, Ọgbẹni Dele Mọmọdu, lo ti sọrọ yii.

Tunde Bakare sọ pe lọdun naa lọhun-un nileewe Liṣabi Grammar School, lọdun 1973, loun ti kọkọ sọ ọ fawọn ẹlẹgbẹ oun pe oun yoo ṣe aarẹ Naijiria lọjọ iwaju. O ni awọn ti oun sọ ̀ọrọ naa loju wọn ṣi wa laye loni-in, nitori pe lati kekere loun ti n wo o pe oun ni nnkan rere ti oun naa le ṣe fun Naijiria lọkan.

Bakan naa lo tun sọ pe lara awọn ti oun ti sọ ọrọ naa fun tipẹ ni Olori ijọ Ridiimu, iyẹn Pasitọ E.O Adeboye, bẹẹ gẹgẹ loun tun sọ fun iyawo oun ki awọn too fẹra awọn sile pe ko kiyesi i, oun yoo di aarẹ Naijiria lọjọ iwaju.

Fun idi eyi, Tunde Bakare sọ pe ki i ṣe pe oun kan ṣadeede ja lu erongba naa bi ko ṣe pe o ti wa lọkan oun tipẹ ni, ati pe aniyan rere toun ni fun Naijiria naa lo fẹẹ mu oun jẹ olori ẹ.

Siwaju si i, ọkunrin ojiṣẹ Ọlọrun yii ti sọ pe oun ko fipa wa a, bẹẹ loun ko ṣetan lati paayan tabi ṣe ohun to lodi si Ọlọrun ki oun le baa di Aarẹ ni Naijiria.

Lọdun 2011 ni Ọgagun Muhammadu Buhari ati Tunde Bakare jọ dije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu CPC, ṣugbọn ti Aarẹ Goodluck Jonathan ati igbakeji ẹ Namadi Sambo ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi ẹyin wọn janlẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin yii ko ti i sọ boya yoo tun jade lẹẹkan si i lọdun 2023, sibẹ ohun to tẹnu mọ ni pe oun n bọ waa ṣe Aarẹ Naijiria lọjọ kan, nitori ipo naa wu oun gidigidi, bẹẹ loun ni ohun rere ti oun fẹẹ ṣe fun awọn ọmọ Naijiria.

Bakan naa lo ti sọ pe ko si iwe adehun kankan laarin oun ati Buhari pe oun ni ọkunrin naa fẹẹ gbe ijọba fun lọdun 2023, bẹẹ lo tun sọ pe ko ti i si ọrọ ajọsọ kankan laarin oun ati Gomina Nasir El-Rufai nipa ajọṣepọ lati dije dupo aarẹ ati igbakeji lọdun 2023.

 

Leave a Reply