Jọkẹ Amọri
‘‘Awọn eeyan ilẹ Hausa lẹtọọ labẹ ofin lati dije dupo aarẹ nigbakugba to ba wu wọ, mo si fẹẹ gba ẹyin eeyan niyanju lati tẹwọ gba ẹnikẹni to ba wọle lẹyin ti esi eto idibo aarẹ yii ba waye lai fi ti ẹtanu ṣe, nitori ọna kan ṣoṣo teeyan fi le bori eto idibo naa ni ki wọn dibo yan an. Bakan naa ni awọn eeyan Oke-Ọya ṣi ni ọdun mẹrin nilẹ ti wọn ko ti i lo nipo aarẹ, ta a ba ṣẹ iye ọdun ti agbegbe kọọkan ti lo’’.
Eyi ni diẹ lara ọrọ ti Alakooso ẹgbẹ awọn agbaagba ilẹ Hausa ti wọn n pe ni Northern Elders Forum (NEF), Ọjọgbọn Ango Abdullahi, sọ niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, lasiko to n sọrọ nibi eto apejọ kan ti wọn ṣe lati fi sami ayẹyẹ ọdun kẹwaa ti wọn da ẹgbẹ awọn agba naa silẹ, eyi to waye ni Sheu Yar’dua Centre, niluu Abuja.
Nbi eto naa ti awọn agbaagba ilẹ Hausa peju si, ni ọkunrin naa ti sọ pe ẹya ilẹ Hausa ṣi ni ọdun mẹrin nilẹ ti wọn ko ti i lo nipo aarẹ. Yatọ si eyi, ẹnikẹni ti ipo aarẹ ba wu lo le dije du u, bo ba dije du u to ba wọle, deede, bi ko ba si wọle naa, deede ni, eyi ko si tun sọ pe ko ma gbidanwo rẹ mọ, nitori ohun ti ofin ilẹ wa sọ niyi.
Abdullahi ni, ‘‘Ofin ilẹ wa ko ruju, o wa nibẹ gedegbe pe mo le dije dupo nigba ogun, ki n si ja kulẹ nigba ogun, ṣugbọn ko yẹ ki ohunkohun le di mi lọwọ lati tun dije lẹyin ti mo ba jakulẹ. Ta a ba tun waa foju ṣẹ iwa ṣe fun mi ki n ṣe fun ọ, tabi fọwọ pa mi lẹyin ki emi naa fọwọ pa ọ lẹyin, ilẹ Hausa ti fọwọ pa ọpọlọpọ eeyan lẹyin ju bi wọn ṣe fọwọ pa oun paapaa lẹyin lọ’’.
O fi kun un pe ko si agbegbe tabi ẹya to fi ara rẹ jin lati jẹ ki orileede yii wa ni iṣọkan to ju awọn eeyan Oke-Ọya lọ, ati pe bi orileede yii ṣe duro to n jẹ Naijiria lonii, ko si ẹya to fara jin fun eleyii lati ṣee ṣe to ju awọn eeyan Oke-Ọya lọ.
‘‘Koda, tẹ ẹ ba n sọrọ nipa iye ọdun ti awọn eeyan ti lo nipo agbara, Ọbasanjọ lo ọdun mẹjọ, Jonathan lo ọdun mẹfa, apapọ rẹ si jẹ ọdun mẹrinla. Umaru Yardua lo ọdun meji, Buhari lo ọdun mẹjọ, o tumọ si pe ọdun mẹrin ni wọn si jẹ wa.
‘‘Ọbasanjọ ko ri ibo ẹgbẹrun mẹwaa niwaju ile rẹ, mo si sọ fun awọn oniroyin ti wọn n sọrọ ṣakaṣaka si i pe ki wọn yee ṣe bẹẹ. Mo sọ fun wọn pe yoo di aarẹ Naijiria pẹlu ibo Oke-Ọya, o si ri bẹẹ, ṣugbọn ọtọ lohun ti wọn fi san an fun wa, wọn ko mọ riri ohun ti a ṣe.
‘‘Awọn wo lo dibo fun Abiọla? Awọn eeyan Oke-Ọya naa lo dibo fun un. Ninu palọ mi nibi yii la ti fẹyin Tofa janlẹ. Oriṣiiriṣii awọn ifaraji bayii ni awọn eeyan Oke-Ọya ti ṣe.
‘‘Ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe boya a ko kun oju oṣuwọn lati dupo, tabi a ko lẹtọọ lati dije dupo. Idi niyi ti a fi n sọ pe a gbọdọ gbe ọrọ oṣelu lorileede yii le ohun ti ijọba awa-ara-wa duro le lori nikan. Aaye pe a n fi ipo naa silẹ fun ẹnikan ko ṣẹlẹ, ti o ba jawe olubori lasiko ibo, a maa gba bẹẹ, ṣugbọn to ba jẹ awa naa la jawe olubori, ko si idi ti ẹnikẹni fi le fi ijawe olubori yii du wa, ko ṣee ṣe ni, a ko si ni i gba rara, awa naa si ti mura silẹ de eleyii.’’
‘‘Ireti awọn eeyan Oke-Ọya ni pe eto idibo yii yoo lọ ni irọwọrọsẹ lai ni eru tabi madaru kankan ninu, gbogbo wa la si gbọdọ gba ẹni to ba bori lasiko idibo naa lai si ẹtanu tabi ikunsinu, ṣugbọn ti ẹnikẹni ba gbe igbesẹ lati da ibo naa ru, awa naa ti ṣetan lati koju iru ẹni bẹẹ.’’ Bẹẹ ni Ango Abdullahi sọ.