Ipo adari ilu di wahala n’Ileṣha-Baruba, ọpọlọpọ eeyan lo fara pa

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ija nla kan bẹ silẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lagbegbe Gukonbu/Kpakotoru, niluu Ilesha-Baruba, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, nitori iyansipo Alhaji Audi Ba’ase (Abiyeruma tilu Ilesha) gẹgẹ bii olori agbegbe Gukonbu/Kpakotoru.

Agbegbe Moshi-Gbofan, niluu Yashikira, nijọba ibilẹ Baruten.

ALAROYE gbọ pe Ọba ilu Ileṣha-Baruba, Ọjọgbọn Halidu Abubakar, lo yan an lati rọpo ẹni to wa nipo naa, ohun ti wọn lo fa a to fi ṣe bẹẹ ni pe iyẹn ko tẹle awọn aṣẹ rẹ.

Eyi la gbọ pe ko dun mọ awọn eeyan kan ninu, to si mu ko di ija igboro laarin igun mejeeji. Bi wọn ṣe yọ ada, ọbẹ atawọn ohun ija oloro mi-in niyẹn, ti wọn si koju ija sira wọn.

Alukoro ajọ NSCDC nipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ aabo ẹni laabo ilu pẹlu awọn ọlọpaa ati ọtẹlẹmuyẹ lo lọọ pana aawọ to ṣuyọ naa.

O ni awọn alakooso ijọba ibilẹ tọrọ naa kan wa sibẹ lati pẹtu si araalu ki wọn gba alaafia laaye.

Afọlabi ni ko sẹni to padanu ẹmi rẹ ninu rogbodiyan naa, ṣugbọn awọn eeyan fara pa, wọn si ti n gba itọju nilewosan.

Leave a Reply