Irin oju ọna Reluwee lawọn eleyii lọọ ji tu tọwọ fi tẹ wọn ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ajọ ẹsọ alaabo sifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara, ni awọn adigunjale meji yii, Waheed Ganiyu ati Mojeed Afọlabi, wa bayii. Lagbegbe Ogbondoroko, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ni wọn ti n ji irin oju ọna Reluwee tu tọwọ fi tẹ wọn.

Alukoro ajọ naa, Ọlasunkanmi Ayẹni, sọ fun awọn oniroyin niluu Ilọrin, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, lọwọ tẹ awọn afurasi naa lasiko ti wọn ṣe akọlu si dukia ijọba, ti wọn tu irin opopona ti Reluwee n rin lagbegbe Ogbondoroko.

O tẹsiwaju pe ọpọ awọn to huwa ọdaran yii ni wọn ko nigbagbọ ninu ọja ọla rere, ti wọn si n ba gbogbo igbiyanju ijọba apapọ lati sọ orile-ede Naijiria dọtun jẹ.

Ayẹni rọ awọn ẹgbẹ fijilante, ki wọn maa wa ni oju lalakan fi n ṣọri nigba gbogbo, ki wọn si maa mu gbogbo awọn kọlọransi ọdaran ti wọn ko fẹ ki orile-ede yii nisinmi lati maa fi wọn jofin.

Leave a Reply