Irọ ni, ijọba ko fọwọ yẹpẹrẹ mu awọn janduku, ohun to yẹ ka ṣe la n ṣe-Lai Muhammed

Adefunkẹ Adebiyi

Nitori bi ẹnu ṣe n kun ijọba apapọ Naijiria lori awọn jandunku to n ṣiṣẹ ibi kiri, awọn apaayan atawọn ajinigbe, ti ọpọ eeyan si n sọ pe ijọba apapọ n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ wọn, Aṣoju ijọba Buhari lẹka iroyin ati aṣa, Alaaji Lai Muhammed, ti ni irọ gbuu ni. O ni ijọba ko fọwọ yẹpẹrẹ mu awọn janduku, ohun to yẹ kawọn ṣe gan-an lawọn n ṣe.

Minisita fun eto iroyin ati aṣa naa sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, lasiko to n dahun ibeere lori eto kan nileeṣẹ NTA.

Alaaji Lai Muhammed sọ pe iwa ọdaran ni janduku ṣiṣẹ, ofin ko faaye gba a, bẹẹ ni ko si labẹ ẹsin tabi irori kan, ohun ti ko daa ko daa ni. Lai sọ pe ẹni to ba jẹ janduku ko lorukọ meji, janduku naa ni, ko baa jẹ afẹmiṣofo. O ni ọwọ kan naa ni ijọba apapọ fi n mu wọn.

“Pe ijọba ko roro mọ awọn janduku gẹgẹ bi wọn ṣe roro mọ awọn to n jijangbara atawọn ọdaran mi-in ki i ṣe ootọ, irọ ni. Iroyin ofege tawọn ti ki i ri nnkan rere n gbe kiri ni.’’ Bẹẹ ni Lai Muhammed wi.

O tẹsiwaju pe iwa omugọ ni yoo jẹ fawọn ṣọja lati fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn apaayan to n pa ṣọja ẹgbẹ wọn ti wọn tun n pa ọlọpaa.

O ni ọna tawọn ṣọja n gba koju awọn eeyan keeyan naa lori ilẹ ati ofurufu ko faaye silẹ fawọn oniṣẹbi ọhun lati tẹsiwaju.

Alaaji Lai fi kun un pe awọn gomina tawọn ẹni ibi n paayan nilẹ wọn naa ti kọ ẹkọ latara aṣiṣe wọn tẹlẹ, wọn si ti gba pe awọn ko ni i ba awọn ọdaran naa sọ asọye kankan, awọn yoo mu wọn, awọn ko si ni i da wọn si ni.

Nigba to tiẹ ti di pe wọn ti dọgbọn si bi ipe ṣe n wọle lawọn ilu ti ifọkanbalẹ ko si naa, ọna tawọn apaayan naa fi n ṣiṣẹ ti dinku gẹgẹ bi Lai ṣe wi.

O ni bi wọn ṣe n fi kẹẹgi ra epo bẹntiroolu lati ileepo kaakiri tẹlẹ ti ko si mọ bayii ti n seso rere lawọn ilu yii. Bakan naa lo ni bijọba ṣe fofin de tita awọn aloku ọkada lawọn ọja kan ti ran awọn eeyan lọwọ, ti wọn si tun ṣofin pe ọkada ko gbọdọ to bẹẹrẹbẹ lọ lojuko kan ṣoṣo.

Gbogbo awọn ilana yii lo ni o daa, to si n mu itẹsiwaju wa ninu ogun awọn janduku apaayan yii, o ni iyẹn ni ko ṣe ni i jẹ ododo ọrọ, bawọn kan ba n sọ pe ijọba n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu wọn.

Leave a Reply