Irọ ni, awọn gomina ilẹ Yoruba ko ko ounjẹ korona pamọ o – Akeredolu

Olusẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Alaga ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu, ti sọ pe ko si ootọ ninu ohun ti awọn kan n gbe kiri pe awọn gomina ilẹ Yoruba tọju ounjẹ to wa fun korona pamọ.

Akeredolu ṣalaye ọrọ yii nibi isin pataki kan ti wọn ṣe lati ṣami ọdun kẹta ti Biṣọọbu ilu Ọwọ, Stephen Fagbemi, ti wa nipo, eyi to waye ni All Saints Church, Idasẹ, niluu Ọwọ.

Gomina ni ohun to jẹ ki o pẹ ki awọn too pin awọn ounjẹ naa faraalu ni pe awọn gomina kan ṣi n duro de awọn ounjẹ mi-in to yẹ ko wọle, ati ipinnu awọn lati ṣefilọlẹ eto pinpin ounjẹ naa ko too di pe awọn berẹ si i pin in.

Arakunrin ni o jẹ ohun to ṣe ni laaanu pe awọn eeyan ja awọn ibi ti wọn ko ounjẹ naa si, ti wọn si n pin in. Bẹẹ lo ni eyi ko ṣẹlẹ nipinlẹ Ondo, nitori bawọn ṣe n gba ounjẹ naa lawọn n pin in faraalu.

O waa ṣeleri iṣẹ takuntakun ni saa keji ijọba rẹ yii.

Leave a Reply