Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni Abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Họnarebu Yakubu Danladi-Salihu, sọ pe irọ ni iroyin kan to n ja ran-in lori ayelujara pe oun fẹẹ dije dupo gomina lọdun 2023.
Ninu ọrọ Danladi, o ni ọsẹ akọkọ ninu oṣu Kejila loun lọ siluu Baruten gbẹyin lati lọọ kopa nibi ayẹyẹ ọdun ibilẹ kan ti wọn pe ni (Gani Festival), eyi to maa n waye lọdọọdun. O ni oun ko ṣe ipade kankan pẹlu ẹnikẹni, ṣugbọn o jọ oun loju pe awọn lẹgbẹ lẹgbẹ ati lọgba lọgba ti n gbe iroyin ofege kiri pe oun ṣepade pẹlu awọn eeyan kan ni Baruten, toun si fifẹ han lati dije dupo gomina lọdun 2023.
O rọ awọn eniyan ipinlẹ Kwara lati takete si gbogbo awọn iroyin to le da rukerudo silẹ laarin ilu ati Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, to n ṣe gudugudu meje ohun yaaya mẹfa nipa pipese ohun amayedẹrun faraalu ni tibu tooro ipinlẹ Kwara, paapaa ju lọ ẹkun idibo Ariwa. Bakan naa lo ni ajọṣepọ to dan mọran wa laarin awọn aṣofin ati gomina. O waa kilọ fun gbogbo awọn to n gbe ayederu iroyin kiri lati lọọ jawọ, ki wọn yee gbe iroyin ofege kiri.