Irọ ni o, ijọba Kwara ko ti i buwọ lu owo-oṣu tuntun-Ajakaye

Stephen Ajagbe, Ilorin

Latari iroyin kan to jade ninu iwe iroyin olojoojumọ kan ta a forukọ bo laṣiiri to n ja kaakiri ori ẹrọ ayelujara pe ijọba ti buwọ lu ẹgbẹrun lọgbọn naira owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ, ijọba ti ni irọ patapata ni, ko si ohun to jọ bẹẹ.

Akọwe iroyin lọfiisi gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye lo, sọ eleyii ninu atẹjade kan lọjọ Aje, Mọnde, o ni ki awọn araalu ma gba iroyin naa gbọ nitori pe ko jade lati ọdọ ijọba.

O ṣalaye pe ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ si n jiroro pọ lati yanju ọrọ owo-oṣu tuntun naa, abajade rẹ yoo si to araalu leti.

Ṣe lati opin ọsẹ to kọja yii niroyin ọhun ti gba ori ẹrọ ayelujara kiri pe ijọba ti buwọ lu owo-oṣu tuntun. Koda, awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ naa kiri ni akọwe iroyin Gomina Abdulrazaq Abdulrahman lo kede ọrọ naa.

Ṣugbọn ìyẹn ko jẹ ki ọrọ ọhun tutu to fi figbe ta pe oun ko gbe ikede tabi atẹjade kankan jade pe gomina fọwọ si owo-oṣu tuntun o, nitori naa, kawọn to n gbe igbekugbee kiri lọọ dakẹ rumọọsi, ki wọn si gbẹnu dakẹ.

 

Leave a Reply