Faith Adebọla
Agbẹjọro fun gbajugbaja ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Sunday Igboho, Amofin Yọmi Aliyu, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ahesọ ọrọ to n ja ranyin pe Sunday Igboho ti bẹ awọn kan lọwẹ pe ki wọn ba oun bẹ Aarẹ Muhammadu Buhari, ki ijọba orileede Bẹnẹ le tete tu oun silẹ, o ni irọ ni, ko sohun to jọ bẹẹ latọdọ Adeyẹmọ.
Ninu atẹjade kan ti lọọya ọhun fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, lori ọrọ naa lo ti sọ pe ahesọ ọrọ ati abamoda lasan ni, ko si oloṣelu kan ti Sunday Igboho tabi iyawo rẹ, Abilekọ Rọpo, bẹ lọwẹ si Buhari.
Atẹjade naa ka lapakan pe:
“Olobo ti to wa leti, a si ti fidi ẹ mulẹ pe awọn oloṣelu kan ti bẹrẹ si i sọ fun onibaara wa, Sunday Igboho, pe ko fawọn laṣẹ ki awọn le gbẹnu ẹ sọrọ lọdọ Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, fun itusilẹ rẹ. O lawọn oloṣelu kan lo wa nidii ọrọ naa, wọn ni ki Sunday Igboho jẹ kawọn fi ọrọ rẹ wa ojuure Buhari, paapaa latari bi awọn ṣe ṣẹṣẹ ta atare sinu ẹgbẹ oṣelu APC laipẹ yii, wọn lawọn fẹẹ ṣe Sunday ati Buhari loore ni.
A fẹ ko di mimọ fun gbogbo aye, titi kan ileeṣẹ Aarẹ paapaa, pe Sunday Adeyẹmọ ki i ṣe oloṣelu, ko si ẹgbẹ oṣelu to fẹran tabi to yan nipọsin, gbogbo wọn ni ọrẹ imulẹ rẹ wa karikari.
Sibẹ naa, o bọwọ fun awọn gomina mẹfẹẹfa ilẹ Yoruba tori wọn n ṣoju ẹya Yoruba ni. Bi atẹjade eyikeyii kan ba wa to ṣafihan pe Sunday Igboho tabi iyawo rẹ ti buwọ luwe, tabi pe o ti yan ẹnikan lati maa gbẹnu sọ foun nileeṣẹ Aarẹ, irọ gbuu ni, ẹ ma ka iru iwe bẹẹ kun rara.
O baayan lọkan jẹ gidi pe oloṣelu ọmọ Yoruba to n wọṣọ abuku kiri ilẹ Yoruba kan, ati ẹṣọ alaabo to ti fẹyinti kan ni wọn lọọ n sọ fun Sunday Igboho pe ko yọnda fawọn lati forukọ wa ojuure ijoba, awọn alailaaanu ẹda yii ko tilẹ ro ti mimu ti wọn mu ọkunrin naa sahaamọ latọjọ yii, ati ipọnju ti wọn n foju ẹ ri, bẹẹ ni wọn o ro ti ipo ailera to n koju ẹ lọwọ lasiko yii, lorileede olominira Benin.”
Ṣugbọn gbara ti atẹjade naa ti gori afẹfẹ lawọn eeyan ti bẹrẹ si i bẹnu atẹ lu minisita feto igbokegbodo ọkọ ofurufu nigba kan, Ọgbẹni Fẹmi Fani-Kayọde, wọn loun ni alatẹnujẹ to le maa dan idankudan-an bii eyi wo, wọn lo fẹẹ fi Sunday Igboho wa ojuure Buhari ni gbogbo ọna ni, tori o mọ pe ẹgbẹ APC to ṣẹṣẹ bọ si yii ko le finu tan oun, wọn ti mọ ọn pe ki i ṣe eku ire rara.
Awọn mi-in to sọrọ lori atẹ ayelujara wọn tun ṣekilọ fun Fani-Kayọde naa pe ti ko ba ṣọra, yoo kan idin ninu iyọ, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ọba alaye kan naa wa nilẹ Yoruba toun naa n tu itukutu lori ọrọ Sunday Igboho.