Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Lojiji niroyin kan gbode lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, pe Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayọde Adetọna, sọ pe ọba tabi aṣaaju Yoruba ti ko ba ti Sunday Igboho lẹyin lasiko yii ki i ṣe ọmọ ọkọ, ọmọ ale ni.
Ṣugbọn nigba to di ọjọ Satide, ọjọ kẹfa, oṣu keji yii, Awujalẹ loun ko sọ ohun to jọ bẹẹ, o ni awọn ti wọn loun sọ bẹẹ purọ mọ oun ni.
Amugbalẹgbẹẹ Awujalẹ, Ọgbẹni Tunde Ọladunjoye, lọba naa fi ọrọ yii ran si gbogbo eti to gbọ alọ, pe ki wọn gbọ abọ ọrọ naa.
Ṣe ohun ti wọn ni Awujalẹ sọ ni pe, ‘‘Gẹgẹ bii ọba alaye tabi aṣiwaju ilẹ Yoruba, o gbọdọ ti Sunday Igboho lẹyin lasiko yii bi o ko ba ki i ṣe ọmọ ale.’’
Ọladunjoye to fi atẹjade sita lorukọ ọba naa sọ pe ‘‘Aafin Awujalẹ ko fi ohun to jọ bẹẹ sita. Gẹgẹ bẹ ẹ ṣe mọ pe olufẹ ilu ati ilẹ Yoruba ni Alayeluwa, o yẹ ka sọ ọ gedegbe pe irọ ni ohun ti wọn ni wọn sọ naa. Ko le baa ye gbogbo eeyan pe ko sẹni to laṣẹ lati fi orukọ kabiyesi gbe iroyin jade lai jẹ ka mọ nipa ẹ la ṣe fi atẹjade yii sita.’’