”Iru ẹlẹnu meji bii Sanwo-Olu ko yẹ nipo olori ijọba l’Ekoo”

Aderohunmu Kazeem

Sannde, ọjọ Aiku yii, ni Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ekoo, Ọgbẹni Taofik Gani, sọ pe pẹlu idaamu ti ipinlẹ Eko ti ri lati nnkan bii ọjọ diẹ sẹyin, ko jọ pe Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣi ni ipa ati agbara lati dari ipinlẹ ọhun mọ, fun idi eyi, ko kọwe fipo silẹ.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii fi kun ọrọ e pe ti ipinlẹ Eko ba ṣi ri bayii fun bii ọjọ mẹta si i, o lo ṣe pataki ki Babajide Sanwo-Olu kọwe fipo silẹ, nitori ohun to foju han bayii ni pe eto akoso ipinlẹ naa ti daru mọ ọn lọwọ.

O ni, “ Iru gomina yii ni mo ri ri, ẹni to sọ pe oun ko mọ bi awọn ṣọja ṣe lọọ kọ lu awọn ọdọ to n ṣewọde ni Lẹkki, ṣugbọn ti awọn ṣọja pada tu aṣiri ẹ pe oun gan-an lo bẹ awọn niṣẹ, ohun to si foju han ni pe iru ẹlẹnu meji bẹẹ ko yẹ nipo olori ijọba nipinlẹ Eko.’’

Alukoro yii fi kun un pe ohun to yẹ ẹ bayii ni ko kọwe fipo silẹ kiakia.  Ati pe awọn eeyan Eko paapaa ko le gba a gbọ mọ lori ipa to ko lasiko rogbodyan SARS.

Lojuẹsẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ti fun awọn PDP lesi, ohun ti wọn si sọ ni pe Gomina Babajide Sanwo-Olu ko ni ipo kankan ti yoo fi silẹ, oun to bẹrẹ saa yii naa lo maa pari ẹ, pẹlu awọn iṣẹ idagbasoke to yaranti to ti n ṣe kaakiri ipinlẹ Eko, gẹgẹ bi ileri ẹ fawọn araalu.

Alukoro ẹgbẹ naa l‘Ekoo, Ṣẹyẹ Ọladẹjọ, sọ pe o jọ pe ọwọ awọn ọmọ egbẹ oṣelu ọhun ko mọ lori wahala to be silẹ ọhun pẹlu ariwo ti wọn n pa pe ki gomina kọwe fipo silẹ nitori rogbodiyan to ṣelẹ l’Ekoo.

Bakan naa lo sọ pe ohun ti wọn sọ yii fi PDP han gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu ti ijakulẹ ti ba laimọye igba nipa ilakaka ẹ lati gba ipinlẹ Eko mọ APC lọwọ, ṣugb̀ọn ti nnkan ko rọgbọ fun rara.

Ọladẹjọ, fi kun ọrọ ẹ pe iṣẹ idagbasoke ko duro l’Ekoo, paapaa bi gomina ṣe bẹrẹ atunṣe oju ọna Ẹlẹkọ si ilu Ẹpẹ, bakan naa lo fi kun un pe eto aabo ati bi igbe aye irọrun yoo ṣe wa fun araalu lo jẹ ijọba Sanwo-Olu logun ju lọ

2 thoughts on “”Iru ẹlẹnu meji bii Sanwo-Olu ko yẹ nipo olori ijọba l’Ekoo”

  1. Sanworo loye kiwon mape kise sanwolu tori iro e poju larin ojo merin si marun oro orishi meta lonso lori isele kan…… #mio o mo bi awon ologun se wa #won o yinbon
    #ati odo awon alagbara lase tiwa #ashiritu #enikankan o ku sugbon awon kan farapa #eyan meji pere loku

    Se awon ibon tiwon yin yen inu afege lonba abi ota ibon aba eyan toun oniku……. won wa nfi IRO se ijoba awon arawon nitori owo , emaro ejo bi esejiko niwaju , iye emi tori owoyinbo , eje alaise reran losi orun aremabo nitori ipo , gbogbo owo Nigeria ti efintoju aeon omotiyin OLOHUN OBA abiyin

    Nikan wa the ogo soju onse bipe ogun ini baba ti e ni Nigeria…… kini awon oluwode ease niwaju ile baba oun nitorinaa won ni ejo je, eyi ti awon ologun naa nso niyen, sanwo _iro naa wanmi ori leyin biti legnenlegbe

Leave a Reply