Iru ki leleyii, Idris lọọ ka ẹlẹhaa mọnu mọṣalaasi, o si fipa ba a lo pọ n‘Ibadan

 Ajao Ọlawale, Ibadan

Awọn ẹgbẹ Musulumi loriṣiiriṣii ni wọn tu jade lọjọ Aje, Mọnde, ọgbọnjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii lati fẹhonu han niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ latari bi ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Idris, ṣugbọn ti inagijẹ rẹ n jẹ Kesari ṣe wọnu mọṣalaasi kan lọ ni Iwo Road, niluu Ibadan, to si lọọ fipa ba ẹlẹhaa to wa ninu mọṣalaaṣi ọhun laṣepọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

Ọmọ ọkan ninu awọn onimọto ni wọn pe ọmọkunrin to yọ wọnu mọṣalaaṣi ọhun, to si fipa ba obinrin to wa ninu aṣọ ẹha lo pọ.

Ibinu ọrọ yii ni awọn agbaagba Musulumi niluu Ibadan, eyi ti gbajumọ oniwaasi nni, Sheik Amubiẹya, dari ṣe fi ẹhonu han ta ko iwa buruku naa.

ALAROYE gbọ pe ọmọ bibi inu ọkan ninu awọn adari ẹgbẹ onimọto ti wọn n pe ni Al-Majiri ni Idris. Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ọmọkunrin naa, wọn si ti mu un lọ si ẹka ileeṣẹ ọtẹmuyẹ awọn ọlọpaa, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.

 Ohun ti awọn ẹgbẹ Musulumi naa n beere fun ni pe ki wọn ma ṣe jẹ ki ọmọkunrin naa lọ lai jiya. Ki wọn fi iya to tọ jẹ ẹ ko le jẹ ẹko fun awọn to ba tun fẹẹ dan iru rẹ wo.


Leave a Reply