Iru ki waa leleyii, awọn oniṣẹẹbi kan gun Motunrayọ pa sinu ile l’Ado-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Inu ibẹru lawọn eeyan 2nd Avenue, to wa laduugbo Aṣeye, lagbegbe Nova, niluu Ado-Ekiti, wa bayii pẹlu bi awọn kan ti ko sẹni to mọ bi wọn ṣe jẹ di akoko yii ṣe pa abilekọ kan, Motunrayọ Ọlajide, sinu ile.

Obinrin ẹni ọdun marundinlaaadọta yii la gbọ pe wọn da ẹmi ẹ legbodo ni nnkan bii aago marun-un irọle Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii.

Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ naa sọ fun ALAROYE pe ọrun ni wọn ti gun oloogbe yii, ṣe lẹjẹ si bo ibi to ṣubu si lasiko tawọn eeyan debẹ. Ọmọ oloogbe to jẹ ọmọ ọdun mọkanla lo de lati ileewe ni nnkan bii aago marun-un aabọ, to si ba oku iya ẹ nilẹ, eyi lo jẹ ko pariwo sita kawọn eeyan too sare wa.

Ẹni to ṣalaye ọrọ naa sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ anfaani pe Motunrayọ maa n saaba wa nile lawọn ẹni ibi ọhun lo, ṣugbọn ko sẹni to mọ nnkan to ṣẹlẹ ti wọn fi gbe igbesẹ dida ẹmi ẹ legbodo.

Kia la gbọ pe awọn lanlọọdu agbegbe naa ti gba ọdọ ọlọpaa lọ lati fọrọ ọhun to wọn leti.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni wọn fi nnkan gun obinrin naa lọrun, oju ọgbẹ naa si jin, eyi to jẹ ko padanu ọpọlọpọ ẹjẹ.

O ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ iṣẹ lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ko ti i mu ẹnikẹni titi di asiko ta a pari akojọpọ iroyin yii.

O waa ni oku oloogbe naa ti wa ni mọṣuari fun ayẹwo lori bi iku ẹ ṣe jẹ gan-an, bẹẹ lawọn ọlọpaa nilo ifọwọsowọpọ awọn eeyan agbegbe naa lati wa awọn to ṣeku pa a lawaari.

Leave a Reply