Iru ki waa leleyii, gbajumọ onifuji kan tun ku n’Ibadan

Kazeem Ọlajide

Lasiko tawọn eeyan ṣi n ṣedaro iku ojiji to pa Oloye Jimọh Aliu lọwọ niroyin mi-in tun jade pe Oloye Sulaimọn Adigun, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Caterpillar ọkọ oke naa ti ku n’Ibadan.

ALAROYE gbọ  pe ṣaaju asiko yii lo ti rẹ ọkunrin olorin fuji yii, ẹni to tun jẹ Ẹkẹrin niluu Lalupọn.

Asiko igba kan tiẹ wa ti iroyin gbalu pe aisan to n ṣe e ọhun ti mu un di ẹlẹsẹ kan.

Ni bayii, ọkunrin naa ti jade laye o, bẹẹ ni wọn yoo sin in nilana Musulumi loni-in.

Lati ri aridaju iṣẹlẹ yii lo mu wa pe Alhaji Kabiru, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Baby Barrister, ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ FUMAN, iyẹn ẹgbẹ awọn onifuji.  Oun naa fidi ẹ mulẹ pe ọkunrin naa ti jade laye, ati pe ninu ipade kan loun wa bayii, nibi ti awọn ti n ṣe aṣaro lọwọ nipa isinku ẹ.

 

Leave a Reply