Iru ki waa leleyii, ileetura ni Teslim wa tawọn adigunjale fi yinbọn pa a n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn adigunjale tun da kun ipenija eto aabo ti ipinlẹ Ọyọ n koju lọwọ bayii pẹlu bi wọn ṣe yinbọn pa ọkunrin alafẹ igboro Ibadan kan to n jẹ Teslim Akinpẹlu.

Ileetura kan ti wọn n pe ni Town Hotel, laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, lawọn adigunjale ẹlẹni mẹrin ọhun ti fibọn ja awọn eeyan lole owo ati dukia wọn mi-in lọjọ Àbámẹ́ta, Satide, to kọja.

Otẹẹli yìí ni Teslim atawọn ọrẹ ẹ ti lọọ ṣe faaji to fi ba iku ojiji pade ni nnkan bíi aago mẹwaa alẹ ọjọ naa.

Awọn adigunjale yii ti n fi otẹẹli ọhún silẹ ki Teslim toun naa fẹẹ kuro nileetu náà lati maa pada sile ẹ ni nnkan bíi aago mẹwaa alẹ too pade wọn

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọkunrin alafẹ yii ko mọ pe awọn adigunjale náà ṣì wa nitosi. Nibi to ti n ba ẹnikan sọrọ lọwọ lori ẹrọ ibanisọrọ lawọn jagunlabi ti yinbọn fun un.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ CSP Olugbenga Fadeyi, fidi ẹ mulẹ pe. O ni, “Awọn òṣìkà eeyan yii dibọn bíi ni to fẹẹ gba yara ninu iteetura naa titi ti wọn fi wọle sí awọn alejo to gba yara nileetura naa lara ni.

O ni yara ti wọn n ṣe oku lọ́jọ̀ sí nileewosan kan nigboro Ibadan ni wọn gbe oloogbe naa lọ ko too di pe wọn sinkú ẹ̀ nilana Musulumi.

Leave a Reply