Iru ki waa leleyii, iwe ni Usman fẹẹ ja fun tirela to fi tẹ ẹ pa n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe ni omije ẹkun gboju awọn eeyan lagbegbe Post Office, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lowurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lasiko ti tirela tẹ ọmọkunrin kan, Usman, pa, nigba to fẹẹ jawee fun dẹrẹba to n wa ọkọ tirela ọhun.

ALAROYE gbọ pe Usman lo fẹẹ jawee fun dẹrẹba to n wa tirela kan lọ labẹ biriiji Post Office, niluu Ilọrin, ṣugbọn tirela ọhun ko duro, Usman fẹẹ gan tirela naa, bi ọwọ rẹ ṣe ja kuro lara ọkọ naa niyẹn, to si ko sẹnu taya tirela, niyẹn ba tẹ ẹ mọlẹ. Niṣe ni ori rẹ fọ, ti ọpọlọ si tu jade.

Dẹrẹba tirela ọhun ko duro, ṣugbọn wọn pada gba a mu ni agbegbe Ọffa Garage, niluu Ilọrin, Wọn ni ọkọ ero Ganmọ si Amọyọ, ni ọkunrin naa n wa tẹlẹ ko too di pe o n jawee fawọn ọkọ.

Awọn ọlọpaa ẹka A Division, niluu Ilọrin, ni wọn pada gbe oku ọkunrin ọhun.

Leave a Reply