Iru ki waa leleyii! Iya ọlọmọ mẹta bẹ sodo toyun-toyun, oku ẹ ni wọn gbejade n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni iṣẹlẹ kayeefi kan ṣẹlẹ lagbegbe Ogidi, niluu Ilọrin, nibi ti obinrin ọlọmọ mẹta to loyun ninu ti bẹ sodo, oku ẹ ni wọn gbe jade ninu odo ọhun.

ALAROYE, gbọ pe arabinrin ọhun ti awọn eeyan mọ si Iya Rasida, lo ji ni owurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, o beere lọwọ ọkọ rẹ pe ṣe o laala kan mọju, ọkọ rẹ to n jẹ Wasiu fun un lesi pe bẹẹ ni, o tun beere pe irufẹ ala wo lo la? Ọkọ ni oun lalaa pe awọn mejeeji n ṣe igbeyawo, ṣugbọn nigba to di alẹ igbeyawo, aburo iyawo ni wọn mu wa fun oun. Ni iyawo ba ni ki ọkọ waa gbe oun lọ si ọdọ Iya Ọṣun kan to wa ni agbegbe odo Moro, l’Okoolowo, niluu Ilọrin, nibi to ti maa n gba itọju pẹlu awọn ẹgbẹ ọrun ti wọn ni o n yọ ọ lẹnu. Ni ọkọ ba ki ọkada mọlẹ, o si gbe e lọ.

Nigba ti wọn de ibi odo Moro yii lọdọ Iya Ọṣun, n jẹ ki ọkọ maa lọ, iyawo ni ki ọkọ duro, lo ba sọ ọmọ to pọn sẹyin kalẹ, lo ba kan lu odo, lo ba n juwọ si ọkọ pe o digba, titi to fi ri sinu odo, ariwo ti ọkọ pa ni Iya Ọṣun gbọ to fi jade ninu ile, wọn bẹ awọn gende lọwẹ lati yọ obinrin naa jade, ṣugbọn oku ẹ ni wọn gbe jade.

Awọn ọlọpaa ti agọ Idi Ọgẹdẹ, ni agbegbe Ọlọjẹ niluu Ilọrin, ni wọn gbe oku naa lọ si agọ wọn, wọn mu Iya Ọṣun ati ọkọ arabinrin naa lọ si agọ wọn lati lọọ sọ ohun ti wọn mọ nipa iku oloogbe ọhun.

 

Leave a Reply