Iru ki waa leleyii, lọjọ ti Habeeb ṣayẹyẹ ikẹkọọ-jade ni Kwara Poli, lo dawati n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Yoruba ni ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni nu lọ, lati Ọjuruu, Wẹsidee, ọṣẹ to kọja  ti Yusuf Habeeb Ọlamilekan ti ṣayẹyẹ ikẹkọọ-jade ni Kwara Poli, to wa niluu Ilọrin, lo ti dawati.
ALAROYE gbọ pe Habeeb ti n dawọọ idunnu, ti awọn obi rẹ si n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ọmọ naa yege, ti owo ti awọn na lori ẹ ko wọ igbo pẹlu bo ṣe pari ileewe rẹ, ti yoo si maa reti iwe ipe lati ọwọ ajọ agunbanirọ ti yoo fi lọọ sinjọba. Sugbọn ayọ naa ti di ibanujẹ bayii lọdọ awọn mọlẹbi rẹ tori pe lati ọjọ ayẹyẹ yii gan-an lo ti dawati, ti ko si si ẹni to mọ ibi to wa titi di akoko ta a n gbe iroyin yii jade.
Awọn mọlẹbi rẹ ti waa rọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Kwara ati orile-ede Naijiria lapapọ pe ibikibi ti wọn ba ti kẹfin Habeeb, ki wọn mu un lọ si agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn ju lọ, wọn ni ọmọ wa o ni i sọnu o, Ọlọrun o si ni i fọmọ pa ẹnikankan lẹkun.

Leave a Reply