Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ara Togo kan, Gbègèlè Mustapha, ti wa nikaawọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, lori ẹsun lilu lanledi rẹ, Abilekọ Adijat Ọlaoye, pa, nibi to ti fẹẹ fipa ba a lo pọ l’Akurẹ.
ALAROYE gbọ pe iṣẹ akọpẹ ni Mustapha n ṣe, o si ti to bii ọdun meje sẹyin to ti n ba awọn eeyan abule Abà-Ọ̀yọ́, n’ijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, ṣiṣẹ ọhun.
Abúlé yii naa loun ati iya ẹni ọdun mejidinlọgọta to ran sọrun apapandodo yii ti pade nipasẹ obinrin nọọsi kan, ẹni to mu awọn mejeeji mọ’ra wọn.
Ko sẹni to mọ ohun ti ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn yii jẹ yo to fi lọọ ka iya oniyaa mọ’nu yara rẹ loru Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un yii, to si fẹẹ ba a sun tipatipa.
Wọn ni ibi ti obinrin naa ti n jijadu lati gba ara rẹ silẹ lọwọ alejo ọran to waa ka a mọ yara loru ọjọ naa lo ti ṣeesi la ori mọlẹ, eyi to pada sọ ọ dero ọrun ọsan gangan.
Girigiri ẹsẹ tawọn araadugbo kan n gbọ ni wọn fi sare wa sibi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si ba Mustapha ninu yara pẹlu lanledi rẹ to sun silẹ. Wọn gbiyanju lati du ẹ̀mí obìnrin naa pẹlu bi wọn ṣe sare gbe e digbadigba lọ sileewosan, nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku.
Ọmọkunrin ọhun ni wọn lo jẹwọ fawọn ọlọpaa ninu ifọrọwerọ ti wọn ṣe pẹlu rẹ lẹyin tọwọ tẹ ẹ pe igbó ti oun mu lọjọ naa lo ti oun nitikuti lati huwa buruku ti oun hu.
Nigba ti akọroyin wa n fọrọ wa afurasi ọhun lẹnu wo lasiko ti wọn n ṣe afihan rẹ ni olu ileesẹ ọlọpaa to wa loju ọna Igbatoro, Alagbaka, niluu Akurẹ, ọrọ rẹ ko ba ara wọn mu, ọtọọtọ lawọn alaye to si ṣe fawọn oniroyin to fọrọ wa a lẹnu wo.
Ninu alaye to kọkọ ṣe fun wa, o ni inu ile loun wa ti oun fi n gbọ ti Mama n pariwo, ‘Togo, Togo’ leyii the to mu ki oun sare lọọ ba a ninu yara rẹ nibi ti oun ti ba a to sun silẹ.
O ni ṣe loun lọ sinu yara lanledi oun lati gba a silẹ lọwọ awọn to waa ṣe ikọlu si i, ati pe biba tawọn eeyan ba oun lọdọ rẹ ni wọn ṣe n pariwo wi pe, ‘Togo, o ti pa a, Togo, o ti pa a’.
Nigba ta a tun pada lọ lẹẹkeji la ti gbọ tẹnu rẹ, igbe awọn ara abule ọhun lo fi bọnu to n pa, o ni awọn ni wọn fẹẹ fi iṣẹlẹ iku iya naa ṣe akoba fun oun latari ododo ọrọ ti oun maa n ba wọn sọ.
Mustapha ni nnkan iṣọra lasan loun n fi awọn oogun bii ijapa, ejo, igbin atawọn nnkan mi-in ti wọn ba ninu yara oun ṣe.