Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ko ṣẹ ni to le ri iya ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun-un kan ti ọmọ rẹ, Abilekọ Abiọdun, dana si lara ti ko ni i ba a kaaanu pẹlu bo ṣe n fi arugbo ara jẹrora ti ko ṣee fẹnu sọ lori bẹẹdi nileewosan to ti n gba itọju lọwọ niluu Ondo.
Iṣẹlẹ yii waye laduugbo Ìdòko,, nile pẹtẹẹsi kan to wa ni idojukọ ṣọọsi nla Cathedral St’ Stephen Anglican, to wa laduugbo Oke-Àlùkò, Suurulere, niluu Ondo, nidaaji Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 ta a wa yii.
Ohun ti ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ to gbomije loju eeyan ọhun ni pe ile ọkọ ni Abiọdun, ẹni tọpọ eeyan mọ si Iya Sunday wa, koda, ọmọ mẹta ni wọn lo ti bi fun ọkọ rẹ. Bẹẹ la tun fidi rẹ mulẹ pe ọdọ iya rẹ, nile wọn to wa ni Cathedral, lo bi gbogbo awọn ọmọ naa si.
Wọn ni ti asiko ati bimọ rẹ ba ti n pe diẹdiẹ nigba to ba ti loyun ni yoo ti ko wa sọdọ iya rẹ, ibẹ ni yoo si wa titi ti yoo fi bimọ ọhun ko too tun gba ile ọkọ rẹ lọ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹrin idaji ni Abiọdun ti kuro nile tirẹ laaarọ ọjọ buruku ta a n sọrọ rẹ yii, to si lọọ jokoo siwaju ile iya rẹ ni Oke-Àlùkò, ko wọle, bẹẹ ni ko fu wọn lara rara pe oun ti wa nitosi.
Bi aago marun-un ṣe n lu ni wọn lo kan ilẹkun pe ki iya oun waa silẹkun fun oun. Iya agbalagba ti ko si ro’kan pe boya aburu kankan le tọwọ ọmọ oun waa ba oun naa dide kabakaba lati oju oorun to wa, o lọọ ṣilẹkun fun ọmọ rẹ.
Iya ko ti i silẹkun tan ti obinirn ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun fi gba ilẹkun mọ ọn lọwọ, o da epo bẹntiroolu to ti mura rẹ silẹ tẹlẹ le iya rẹ lori, bẹẹ lo ṣana si i loju-ẹsẹ.
Awọn araale pẹlu iranlọwọ awọn eeyan to wa laduugbo gbiyanju lati pana to wa lara iya yii nigba ti wọn sare de ibi ti iya naa ti n pariwo igbe oro. Wọn sare gbe mama yii lọ si ọsibitu fun itọju, ti wọn si fa Abiọdun to jẹ eku ẹda le awọn ọlọpaa to wa ni tesan Ẹnu-Ọwá lọwọ.
Nigba ti wọn n fọrọ wa ọdaju ọmọ ọhun lẹnu wo ni teṣan, alaye ti wọn lo ṣe fun wọn ni pe pasitọ kan ti oun lọọ gbadura lọdọ rẹ lo riran si oun pe iya oun gan-an lẹni to n ṣe oun, eyi lo fa a ti oun fi gbe igbesẹ naa.
Awọn agbofinro ni ko si wahala, wọn ni ko juwe ile ojisẹ Ọlọrun to ri iru iran bẹẹ si i kawọn le tete lọọ fi pampẹ ofin gbe e, ni iya ọlọmọ mẹta ọhun ba tun yi ọrọ rẹ pada, o ni mama oun gan lẹni to mu oun lẹyin lọọ ba iya kan fun ayẹwo.
O ni bi awọn ṣe fẹẹ kuro nibẹ ni iya tawọn lọọ ṣe ayẹwo lọdọ rẹ fi ọgbọn pe oun pada, to si la a mọlẹ fun oun pe iya to bi oun gan-an ni eleṣu lẹyin oun, nitori oun lo wa nidii ọrọ aye oun.
A gbọ pe awọn ọlọpaa ti ni ati pasitọ o, ati iya to darukọ lawọn yoo lọọ fi pampẹ ofin gbe wa si teṣan, ṣugbọn akọroyin wa ko ti i fidi ẹ mulẹ boya awọn agbofinro ti gbe igbesẹ naa.
Ọdọ awọn ọlọpaa Ẹnu-Ọwá ni Abiọdun ṣi wa titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo. Bẹẹ ni iya rẹ ṣi wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun ni ọsibitu ti wọn ti n tọju rẹ lọwọ, ti gbogbo ori, oju, ọwọ ati ẹyin rẹ si ti bo fẹlẹfẹlẹ latari ina buruku ti ọmọ bibi inu rẹ da si i lara.