Iru ki waa leleyii, Pasitọ Ajigbọtoluwa tun fun tẹgbọn-taburo loyun l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iranṣẹ Oluwa lawọn eeyan mọ baba ti ẹ n wo yii si l’Olomoore, l’Abẹokuta. Ebenezer Ajigbọtoluwa lorukọ ẹ. Ṣugbọn oun funra ẹ ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun ba awọn ọmọ iya kan naa lo pọ, oun fun wọn loyun bi ọjọ ori wọn ti kere to, oun si ba wọn ṣẹ ẹ pẹlu.

Orukọ ṣọọṣi ti pasitọ yii n dari ni ‘The Church Of The Lord’, Abẹokuta lo wa. Ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16) ati mẹtala (13) lawọn ọmọ to fun loyun naa gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun ṣe ṣalaye.

Iya awọn ọmọ yii lo n ṣaarẹ lọdun 2018, ni wọn ba gbe e lọ si ṣọọṣi Ajigbọtoluwa. Nigba naa ni pasitọ paṣẹ pe ki obinrin naa ati idile rẹ maa waa gbe ni ṣọọṣi, ki aarẹ to n ṣe iya ma baa tun fọwọ kan awọn ọmọ.

Nibi ti wọn ti n gbe ṣọọṣi lo ti di pe pasitọ n ba awọn ọmọ naa sun, o si ba wọn sun titi ti wọn fi loyun fun un. Pasitọ lo mu awọn ọmọ naa lọọ ṣẹyun ọhun nile iwosan aladaani kan.

Yatọ si eyi, miliọnu meji naira ni wọn lo gba lọwọ idile obinrin yii fun itọju arun to loun n wo, o lu wọn ni jibiti gidi.

Nigba ti aṣiri tu, pasitọ sa lọ. Awọn ọlọpaa wa a titi ki wọn too ri i mu lọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ yii, oun naa si ti jẹwọ pe ọpọlọpọ ẹsun ti wọn mu oun fun loun jẹbi ẹ

 

 

Leave a Reply