Iru ki waa leleyii, wọn lawọn ṣọja ti n yinbọn fawọn oluwọde ni Lẹkki

Nnkan ko rọgbọ fun awọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde ni Lekki ti wọn ni awọn ko ni i kuro nibi iwọde naa bo tilẹ jẹ pe ijọba ti ṣofin konilegbele.

ALAROYE gbọ latẹnu awọn to wa nibẹ pe awọn ṣọja pẹlu mọto bii mẹwaa lo ya bo wọn lojiji lẹyin ti wọn ti pa gbogbo ina oju popo to wa nibẹ ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn fun awọn eeyan naa nibi ti wọn kora jọ pọ si.

Ariwo ati ẹkun pẹlu idarudapo lo gba agbegbe naa kan, bẹẹ lawọn to wa nibẹ si n pariwo kikan kikan.

ALAROYE ko ti i le fidi rẹ mulẹ boya eeyan ku tabi bẹẹ kọ. Ṣugbọn ọwọ ti ibọn fi n ro lakọ lakọ nibẹ ninu fidio kan ti a ri da bii oju ogun ni, o si mu ibẹrun gidi lọwọ.

One thought on “Iru ki waa leleyii, wọn lawọn ṣọja ti n yinbọn fawọn oluwọde ni Lẹkki

  1. Erii pe eleyii ga bayii. Ùn emiun sọ pé àṣejù t’iwo iwode yí kilode so’ja kogbo ìreegbà ibitiwon ranwonde wajise depe ìjọba kosi gbọdọ wo ran o

Leave a Reply