Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Awọn ọbayejẹ ti pa baba agbalagba kan, Alagba Matthew Malik, sinu igbo niluu Ọyẹ-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ.
ALAROYE gbọ pe oloogbe naa to jẹ ẹṣọ alaabo ni Fasiti ijọba apapọ to wa niluu naa, Federal University Oye (FUOYE), lo lọ soko, ṣugbọn tawọn eeyan ko ri i nigba to yẹ ko bẹrẹ iṣẹ nirọlẹ, eyi lo si jẹ ki wọn bẹrẹ si i wa a.
Nigba ti wọn de oko baba ẹni ọdun mejilelọgọta ọhun ni wọn ba a nibi tawọn kan pa a si, ami si wa pe o dura ko too jade laye.
Ko sẹni to mọ nnkan to ṣẹlẹ ninu igbo naa, ṣugbọn a gbọ pe ẹnikan wa ti wọn jọ ni gbolohun asọ, awọn mọlẹbi ẹ si n woye pe o ṣee ṣe ki ẹni naa lọwọ ninu iku ẹ.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe awọn ti gbọ nipa ẹ, iwadii si ti bẹrẹ lati mọ awọn to ṣiṣẹ ibi ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, bii ọsẹ meji sẹyin lawọn kan pa Pasitọ Kayọde Ogunlẹyẹ sinu igbo kan to wa lọna Aramọkọ-Ekiti si Ijero-Ekiti, awọn araalu si fura pe awọn darandaran lo da ẹmi oloogbe to tun jẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti naa legbodo.