Iru ki waa leleyii! Wọn ṣa eeyan marun-un pa ni Mọdakẹkẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Titi di asiko ti a n koroyin yii jọ, ko sẹni to mọ awọn ti wọn pa eeyan marun-un ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu Mọdakẹkẹ nidaaji ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, loju-ọna abule kan ti wọn n pe ni Toro.

Ṣe ni wọn ṣa awọn eeyan naa ladaa lori yannayanna, ti ẹjẹ si bo gbogbo wọn.

Eleyii si ti da ibẹru-bojo silẹ laarin ilu Mọdakẹkẹ ati Ifẹ, gbogbo agbegbe Mayfair, Lagere, ati bẹẹ bẹẹ lọ, lawọn eeyan ti n tilẹkun ṣọọbu wọn bayii fun ẹru nnkan to le ṣẹlẹ.

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ iṣekupani naa, o ni kọmiṣanna ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati ṣeto aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

A gbọ pe wọn ti ko oku awọn maraarun lọ sile igbokusi ileewosan OAUTHC niluu Ileefẹ.

Leave a Reply