Isin aisun ọdun tuntun ko gbọdọ kọja aago mẹwaa alẹ l’Ekoo- Sanwo-Olu

Faith Adebọla, Eko

 Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ti sọ pe loootọ nijọba ipinlẹ Eko ko wọgi le ayẹyẹ aisun ọdun tuntun ku ọla to maa n waye lawọn ileejọsin lalẹ ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, sibẹ, gbogbo ileejọsin gbọdọ pari eto isin wọn lalẹ ọjọ naa, ko gbọdọ kọja aago mẹwaa.

Ọrọ yii wa lara ohun ti Gomina Sanwo-Olu sọ nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nile ijọba to wa ni Marina, l’Ekoo, l’Ọjọbọ, Tọsidee yii. O ni dandan ni kawọn ileejọsin bọwọ fun aṣẹ ifidimọle tijọba apapọ ṣẹṣẹ ṣe, pe ko gbọdọ si lilọ bibọ ọkọ tabi eeyan kan laarin aago mejila oru si aago mẹrin owurọ kaakiri gbogbo ipinlẹ lorileede yii.

Gomina ni gbogbo awọn aṣaaju ẹsin kaakiri ipinlẹ yii gbọdọ jẹ ki ọrọ naa ye awọn ọmọ ijọ wọn daadaa, tori ipinlẹ Eko ko ni i gba gbẹrẹ lori ofin naa, ati pe fun anfaani araalu ni ofin yii wa fun, lati mu adinku ba itankalẹ arun Korona to tun ti n gberi lẹẹkeji nipinlẹ Eko, ati ni Naijiria.

O ni oun mọ pe nnkan idunnu ni lati la ọdun kan ja si ekeji, ṣugbọn bo ba ṣe gba lasiko yii ni konikalu ṣe e, nitori aabo ati alaafia wa ni.

Eyi ni igba akọkọ ti Gomina Babajide Sanwo-Olu yoo jade sita lati ba awọn oniroyin sọrọ latigba to ti wa ni iyasọtọ nitori arun Korona to lugbadi rẹ, ṣugbọn ti Akọwe iroyin rẹ, Gbenga Akosile, kede lonii pe o ti gbadun daadaa bayii.

Leave a Reply