Isinmi ranpẹ ni ẹgbẹ APC lọ l’Ọṣun, ọdun 2026 ni opin PDP

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ijọba apapọ orileede yii ti pari gbogbo eto lati kọ ilegbee olowopọọku kaakiri awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji ati olu ilu ilẹ wa, Abuja, lati din inira tawọn araalu n koju lati di onile ku.

Ilegbee naa, eyi to jẹ ẹgbẹrun lọna aadọta, nijọba apapọ yoo gbe owo iṣẹ naa jade laipẹ yii, gẹgẹ bi Alakoso iṣẹ ni ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si kikọ ilegbee fawọn araalu, Executive Director (Project Implementation) Federal Housing Authority, Ọnarebu Olurẹmi Ọmọwaiye, ṣe ṣalaye.

Nibi eto iranwọ owo kan, eleyii ti Ẹnjinnia Kayọde Ṣowade, gbe kalẹ fun awọn eeyan ilu Mọdakẹkẹ, ni Ọmọwaiye ti sọ pe loootọ ni oniruuru ipenija n dojukọ awọn ọmọ orileede yii bayii, ṣugbọn gbogbo ọna lati fopin si i ni Aarẹ Tinubu n san.

O ni awọn ti wọn mọ nipa ile kikọ nipinlẹ kọọkan ni wọn yoo ṣiṣẹ nibi awọn ilegbee olowopọọku naa, eyi yoo si tun mu ki eto ọrọ-aje tun rugọgọ si i kaakiri awọn ijọba ipinlẹ.

Ọmọwaiye ke si awọn araalu lati fi ara da a diẹ si i fun Aarẹ Tinubu, nitori tita-riro la a kọla, gbogbo nnkan ti igbẹyin rẹ yoo ba dara ni iberẹ rẹ si maa n lọ jaijai.

Ninu ọrọ tirẹ, Ẹnjinnia Kayọde Ṣowade ṣalaye pe oun pe eto naa ni ‘Oyetọla Hand of Fellowship’ lati jẹ kawọn eeyan ilu Mọdakẹkẹ mọ pe ẹgbẹ APC ko gbagbe wọn rara.

O ṣalaye pe igba kẹrin niyi ti oun gbe eto naa kalẹ, oun yoo si tẹsiwaju titi di ọdun 2026. O ni, lapapọ, ẹgbẹrun mẹta din diẹ ni awọn ti wọn ti janfaani eto naa.

Ṣowade sọ siwaju pe eto naa ki i ṣe ti ẹgbẹ oṣelu tabi ẹsin tabi ẹya kankan, bi ko ṣe fun gbogbo awọn eeyan ilu abinibi oun, Mọdakẹkẹ.

Bakan naa ni ẹni to ṣoju Alhaji Gboyega Oyetọla to jẹ minisita fun ọrọ okoowo ori omi nilẹ yii nibi eto naa, Ọnarebu Festus Babatunde Kọmọlafẹ, sọ pe isinmi ranpẹ ni ẹgbẹ APC lọ nipinlẹ Ọṣun, ọdun 2026 si ni opin ranhun-ranhun ti ẹgbẹ PDP n ṣe bayii.

O ke si awọn araalu lati ni ipinnu ọkan, ki wọn bẹrẹ ipalẹmọ lati le ẹgbẹ PDP wọle, ki wọn si tẹ siwaju lati gbaruku ti ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu.

Leave a Reply