Israel Adesanya, ọmọ Naijiria to n ja ijakadi fagba han wọn ni Abu Dhabi

Ọmọ ilẹ wa to n ja lagbo ijakadi Ultimate fighting Championship (UFC), Israel Adesanya, ti fitan tuntun balẹ bayii pẹlu bo ṣe di ami-ẹyẹ Middleweight Champion mu lẹyin to na Paulo Cpsta ilẹ Brazil.

Ija naa to waye niluu Abu Dhabi, nilẹ United Arab Emirate, ni Costa fẹẹ lo lati gba ami-ẹyẹ to wa lọwọ Adesanya ọhun, ṣugbọn nnkan ko ri bi ara Brazil naa ṣe ro.

Awọn mejeeji ko fi bẹẹ lu ara wọn nipele akọkọ ija naa, ṣugbọn nigba to di ipele keji ni Adesanya fi ẹṣẹ ati ipa da batani si Costa lara, nigba ti ẹjẹ si bẹrẹ si i da lori ẹ ni nnkan yiwọ fun ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ọhun.

Ifarapa ọhun lo mu Costa ṣubu nigba to ya, ni Adesanya, eni ọdun mọkanlelọgbọn, ba da ẹṣẹ bo o ki adari ija too sọ pe ko ma pa ọmọlọmọ foun. Lẹyin ija naa, o fara han pe Costa yoo de ileewosan kara ẹ too ya.

Ni bayii, Adesanya ti ja ija ogun (20) lagbo MMA to jẹ agbo awọn to n lo ẹṣẹ, ipa atawọn ilana ijakadi mi-in, bẹẹ ni ko fidi-rẹmi ri.

Fun Costa, eyi ni igba akọkọ yoo fidi-rẹmi ninu ija mẹrinla.

Leave a Reply