Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Gbogbo awọn to gbọ pe ọmọkunrin kekere kan tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ti tẹ bayii, Issa Naigheti, ji baba to bi i gbe, to si gba miliọnu meji aabọ Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ ni ọrọ naa n ṣe ni kayeefi.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lo ti salaye pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ ọmọdekunrin afurasi kan lagbegbe Kambi, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara, to si jẹwọ pe loootọ ni oun ji baba oun Bature Naigboho, gbe niluu Igboho si Igbẹti, nipinlẹ Ọyọ, toun si gba miliọnu meji aabọ gẹgẹ bii owo itusilẹ lọwọ rẹ.
Ajayi ni ileesẹ ọlọpaa yoo gbe afurasi naa lọ si ipinlẹ Ọyọ to ti huwa ọdaran naa.