Iwa ọdaju ati ailaaanu araalu ni bijọba Eko ṣe fẹẹ ṣi too-geeti Lẹkki pada-Bọde George

Adewumi Adegoke

Ọkan ninu awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bọde George, ti sọ pe oun yoo lọ sile-ẹjọ lati da ṣiṣi too-geeti Lekki to ti wa ni titi lati bii ọdun kan aabọ sẹyin tijọba n gbero lati ṣi pada duro. O ni iwa ika, ailaaanu ni bi wọn ṣe fẹẹ si i pada.

Bọde George, ẹni to fi aidunnu rẹ lori ọrọ yii han fawọn oniroyin lopin ọsẹ to kọja sọ pe niṣe lo yẹ ki ijọba ipinlẹ Eko wo too-geeti ti wọn kọ sibẹ naa palẹ patapata, ki wọn si pa a rẹ ko ma si nibẹ mọ. O ni igbesẹ yoowu ti wọn ba gbe lati ṣi i pada da bii pe wọn jẹ ọdaju eeyan, wọn ko laaanu araalu loju, bẹẹ ni awọn ko si ni i gba iru eleyii laaye.

Alaga Ọmọ Eko Pataki yii sọ pe o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ ati iwa aibikita pe awọn kan tun n ronu pe wọn fẹẹ ṣi too-geeti Lekki pada lasiko ti inira ti ki i ṣe kekekre wa fawọn araalu, to si ṣoro fun idile mi-in lati ri ounjẹ ẹẹmẹta jẹ loojọ; ti ọpọ to n wọ mọto ko rowo ọkọ naa; to si nira fun awọn obi lati sanwo ileewe awọn ọmọ wọn to ti di gegere; ti ọpọ ayalegbe ko si le san owo ile wọn.

O ni o ṣe ni laaanu pe iru asiko ipọnju buruku yii ni ijọba ipinlẹ Eko tun fẹẹ di kun ajaga to ti wa lọrun awọn eeyan ipinlẹ Eko tẹlẹ, ti wọn si tun fẹẹ da too-geeti paada.

Bọde Geeorge ni ọna lati wa owo ti Tinubu yoo fi polongo fun eto idibo rẹ sipo aarẹ to ti ku ko too bẹrẹ rẹ rara lati ni wọn n wa, igbesẹ yii ko si fi wọn han bii aṣiwaju rere, ko si fi wọn han bii ẹni to ni ifẹ araalu lọkan.

Tẹ o ba gbagbe, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, ni wahala nla bẹ silẹ ni Lekki too-geeti yii lasiko tawọn ọdọ n fẹhonu han tako awọn ọlọpaa SARS ti wọn n pa awọn ọdọ nipakupa. Ifẹhonu han naa ni wọn n ṣe lagbegbe too-geeti yii tawọn ṣọja fi ya bo wọn, ti wọn si pa ọpọ ninu wọn.

Ibinu iṣẹlẹ yii ni wọn fi ba too-geeti naa jẹ, ti ko si ṣee lo fun awọn ileeṣẹ to n gba owo nibẹ.

Lọsẹ to lọ lọhun-un ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa jade pe awọn fẹẹ si i too-geeti ti wọn ti n pawo rẹpẹtẹ yii pada lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti wọn si ni ọfẹ ni awọn to n gbabẹ yoo maa kọja fun ọjọ mẹẹẹdogun, wọn ko ni i san kọbọ.

Lẹyin ọjọ mẹẹẹdogun yii ni wọn ni awọn yoo bẹrẹ si i gbowo lọwọ wọn.

Leave a Reply