Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Iwadii ti bẹrẹ lori iku ojiji to pa oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ (DSS) kan latọwọ ṣọja kan to gun un lọbẹ pa lọjọ Satide to kọja yii niluu Ado-Ekiti.
Irọlẹ ọjọ Abamẹta naa niṣẹlẹ yii waye nileetura kan to wa lọna ileeṣẹ NTA, l’Ado–Ekiti.
Bo tilẹ jẹ pe oriṣiiriṣii lawọn eeyan n sọ nipa bo ṣe ṣẹlẹ, ohun to foju han lai ruju ni pe ọkan ninu awọn ṣọja to wọ ile itura naa lọjọ yii binu tan, o fa ọbẹ yọ, o si fi gun ọtẹlẹmuyẹ ọhun nibi to lewu, to bẹẹ to jẹ niṣe lọkunrin naa dagbere faye.
Ẹnikan to ba wa sọrọ nileetura naa to ni ka ma darukọ oun ṣalaye pe mẹta lawọn ṣọja to wa sọdọ awọn lọjọ naa lati ṣe faaji. O ni lojiji ni wọn ri ọmọkunrin kan to jẹ ọmọ Yahoo, wọn si da a duro lati fi ọrọ wa a lẹnu wo lori iṣẹ to n ṣe.
Ifọrọwanilẹnu wo naa lo ni ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ, nitori o jọ pe ẹru ti n ba ọmọ Yahoo nigba tawọn ṣọja n fibeere po o nifun pọ. Nigba naa ni ọmọ Yahoo ṣẹwọ si oṣiṣẹ DSS to wa nitosi wọn nibẹ pe ko waa gba oun lọwọ awọn ṣọja ti wọn fẹẹ gbe oun sọkọ lọ yii.
O ni ọkunrin DSS naa gbiyanju lati ba awọn ṣọja yii sọrọ pe ki wọn ma mu ọmọ naa lọ, ki wọn fi ya oun. Ṣugbọn eyi ko tẹ awọn ṣọja lọrun, ọrọ naa di ariwo laarin wọn. Nigba naa lo ni ṣọja kan fa ọbẹ yọ to si fi gun DSS, ni wahala ba de.
Ẹjẹ to danu lara oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ naa pọ, ohun to si fa iku rẹ niyẹn. Awọn ọtẹlẹmuyẹ bii tiẹ ti wọn to mẹfa ni wọn pada ya bo ileetura naa gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn si lo agbara wọn lori awọn ṣọja yii, wọn ko wọn lọ.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ti mu ṣọja to gun eeyan pa naa ju satimọle, awọn si ti bẹrẹ iwadii gidi lori iṣẹlẹ yii, ki idajọ ododo le waye bo ṣe yẹ fẹni ti wọn gun pa.