Iwadii bẹrẹ lori bi awọn olowo-ori ṣe ti akẹkọọ m’ọnu ọgba ileewe l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

 

Ijọba ipinlẹ ti fesi lori fidio kan to jade sori intanẹẹti laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ninu eyi ti obinrin kan ti pariwo pe ẹka to n pawo wọle labẹnu fun ipinlẹ naa, Ekiti State Internal Revenue Service, ti awọn ọmọleewe alakọọbẹrẹ mọ ọgba ileewe wọn.

Ninu fidio ọhun ni obinrin naa ti ni agbegbe Baṣiri, l’Ado-Ekiti, nileewe ọhun wa, niṣe ni ẹka ijọba ọhun si ti geeti ileewe naa pa, bẹẹ ni wọn ko pada wa lati ṣi i.

O ni awọn alaṣẹ ileewe ọhun ti pe awọn to ti geeti ọhun, ṣugbọn wọn ko dahun, bẹẹ iya ni wọn fi n jẹ awọn ọmọ keekeeke ti wọn ti mọle.

Nigba to n fesi, Kọmiṣanna feto iroyin, Ọnarebu Akin Ọmọle, sọ pe iwadii ti bẹrẹ kia lori iṣẹlẹ naa, ati pe awọn alaṣẹ ileewe ọhun ti sọ pe ko sẹni to ti ọmọ mọ ibẹ.

O waa ni eyi ko ni i di iwadii to n lọ lọwọ, ijọba ko si ni i gba ki ẹnikẹni fiya jẹ araalu, bẹẹ ni esi iwadii yoo jade laipẹ.

Leave a Reply