Iwadii bẹrẹ lori ijamba ina to paayan mẹta n’Ikẹja

Faith Adebọla, Eko 

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti lawọn maa tọpinpin, awọn yoo si jẹ karaalu mọ ohun to ṣokunfa ijamba ina nla kan to waye lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee yii, niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, ninu eyi ti eeyan mẹta ti dagbere faye, awọn mẹtala si fara gbọgbẹ yannayanna.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, lo ṣọrọ ọhun nigba to ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ ni deede aago mejila ọganjọ oru ọjọ naa.

Odumosu ni ko ti i ṣeni to le sọ pato ibi ti ina naa ti wa, ṣugbọn ohun kan to daju ni pe awọn ileeṣẹ to n pọn afẹfẹ gaasi ati epo bẹntiroolu to wa nitosi maa wa lara ohun to mu ki ina naa ṣọṣẹ gidi.

Atẹjade kan lori iṣẹlẹ ọhun, eyi ti ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorileede yii, National Emergency Management Agency (NEMA), ẹka ti Eko, fi lede laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, fidi ẹ mulẹ pe awọn mẹta lo ti doloogbe, wọn lawọn mẹta ọhun, oṣiṣẹ ile ounjẹ Chinese kan to wa nitosi otẹẹli Sheraton ni wọn, wọn l’Ọgbẹni Balogun to jẹ maneja ile ounjẹ naa wa lara awọn to ku.

Alukoro NEMA, Ọgbẹni Ibrahim Farinloye, to buwọ lu atẹjade ọhun sọ pe awọn doola ẹmi awọn mẹsan-an ti ina naa ka mọ, ṣugbọn wọn ti fara gbọgbẹ gidi, tori ina naa ti mu wọn ki wọn too ri wọn fa jade, ti wọn si sare gbe wọn lọ sọsibitu ijọba to wa n’Ikẹja.

O lawọn mẹrin mi-in tun fara pa nibi akọlu to ṣẹlẹ nigba tọrọ di bo-o-lọ-o-yago latari bawọn eeyan ṣe n sa asala fun ẹmi wọn.

Bakan naa lo lawọn o ti i le sọ pato ohun to ṣokunfa ijamba naa, ṣugbọn iwadii ti n lọ lọwọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa Eko.

Ohun ta a gbọ, gẹgẹ bi Ọgbẹni Rotimi Ọlawale to n gbe lagbegbe ọhun ṣe sọ f’ALAROYE ni pe “Ojiji lawọn ṣadeede gburoo ariwo kan to da bii ki agba gaasi bẹ, ko si pẹ ti iro buruku naa dun lawọn tun ri i pe ina ti ṣẹ yọ, ina naa si lagbara gidi.

“Nitori ọpọ eeyan ti wọle sun, oju oorun niṣẹlẹ naa ti ba wọn, ko si seeyan to mọ ibi ti ina naa ni n bọ, ikọlukọgba nla lo ṣẹlẹ, tonikaluku bẹrẹ si i sa asala fẹmii wọn, ki ina naa ma lọ ka wọn mọle.

“Ẹgbẹ otẹẹli Sheraton to wa loju ọna Mobọlaji Bank-Anhony, lo ti ṣẹlẹ, ileepo Total kan si wa nibẹ, ileeṣẹ ti wọn ti n ta afẹfẹ gaasi idana kan tun wa nitosi, a si ri tanka epo diisu kan to n ja epo lọwọ lagbagbe naa lasiko tiṣẹlẹ naa waye.

“Ina naa ti jo supamakẹẹti Oasis kanlẹ, o si ti mu otẹẹli Sheraton to wa lẹgbẹẹ ẹ. Gbogbo awọn alejo to wa ninu otẹẹli ti bẹ sita, ṣun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ ti ṣẹlẹ loju popo, kaluku lo n wa ọna lati sa asala.” Ọgbẹni Ọlawale lo ṣalaye bẹẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe ko pe tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana fi de sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si tete kapa ina ọhun.

Leave a Reply