Iwadii fihan pe ko si aisan kankan lara Adegoke titi to fi ku – Dokita 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Dokita akọṣẹmọṣẹ nipa ayẹwo si ara oku (Consultant Pathologist), to n ṣiṣẹ pẹlu ileewosan UNIOSUNTHC, Oṣogbo, Dokita Waheed Akanni Oluogun, ti sọ pe ninu ayẹwo ti oun ṣe si oku Timothy Adegoke, ko si aisan kankan lara rẹ titi digba to ku.

Timothy, akẹkọọ Fasiti Ifẹ lo ku sinu otẹẹli Hilton, niluu Ileefẹ, lọjọ karun-un oṣu Kọkanla, ọdun to kọja. Latigba naa si ni oludasilẹ ileetura ọhun, Dokita Rahmon Adedoyin ati mẹfa lara awọn oṣiṣẹ rẹ si ti n jẹjọ lori iku ọkunrin yii.

Lọsẹ meji sẹyin ti igbẹjọ naa, eleyii to n waye ni Court 1, niwaju adajọ-agba fun ipinlẹ Ọṣun, Onidaajọ Adebọla Adepele-Ojo, bẹrẹ, ni mọlẹbi oloogbe kan, iyawo oloogbe ati ẹgbọn rẹ ti jẹrii.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ni dokita akọṣẹmọṣẹ naa jẹrii nipa gbogbo nnkan to ri. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, “Mo gba ipe latọdọ Inspẹkitọ Afeez Ọlaniyan lọsan-an ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, pe ki n darapọ mọ wọn nibi kan ti wọn ti fẹẹ hu oku kan niluu Ileefẹ.

“Nigba ti mo debẹ, mo ba ọlọpaa bii mẹrin nibẹ, awọn mọlẹbi oloogbe mẹta darapọ mọ wa, igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa kan naa si wa nibẹ.

“Nibẹ, wọn sin oku yẹn sibi ti ko jinna rara si ojuupopo, loju-ọna Ifẹ/Ẹdẹ Road, nitosi geeti OAU. Ibi ti wọn sin in si da bii ibi ti wọn maa n da ilẹ si (Dumping site). Nigba ti a hu u jade, ẹjẹ wa ni gbogbo ara aṣọ-bẹẹdi ti wọn fi yi i, ko si si ẹya ara rẹ kankan to han sita.

“Oke lo kọju si, wọn si di i lokun lọrun ati ni ibi orunkun. Idin wa labala apa-osi ori rẹ ati ibi ẹsẹ rẹ. O wọ aṣọ pupa ati sokoto pempe. Ẹgbọn oloogbe, Olugbade Adegoke, si fi ika ẹsẹ (toe) da a mọ pe Timothy ni.

“Lẹyin eyi ni a gbe oku yẹn lọ sileewosan wa l’Oṣogbo fun ayẹwo, a si gbe e sile igbokuu-si titi di ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla yẹn ti a ṣe ayẹwo si oku lara. Awa akọṣẹmọṣẹ meje la wa nibẹ lọjọ naa.

“Ninu ayẹwo wa, ẹjẹ didi wa ni abala ọwọ-ọtun aya rẹ (right chest), apa (fracture) wa nibi eegun abala apa-osi ni ọrun rẹ. Amọ ṣa, ko si ami pe wọn ge nnkan kan nibi ọrun rẹ, bẹẹ ni ko si ami pe ẹjẹ ṣan ni ọrun rẹ.

“Bakan naa, ko si ẹran-ara kankan to bo abala ọwọ oke ẹsẹ rẹ, bẹẹ ni eegun ọrun-ọwọ osi ati ti igunpa rẹ ti yẹ, ṣugbọn gbogbo ẹya ara rẹ lo pe perepere, awọn bii kidinrin, ọkan, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

“Ni ero temi, mo le sọ pe ẹjẹ pupọ to jade lara ọkunrin naa nipasẹ inira (Severe haemorrhage, secondary to severe traumatic injury) lo ṣokunfa iku rẹ.

Nigba to n dahun ibeere lọdọ awọn agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Oluogun sọ pe loootọ loun ko mọ Adegoke ko too ku, bẹẹ ni oun ko mọ nipa ilera rẹ, ṣugbọn ayẹwo fihan pe gbogbo ẹya ara rẹ ni wọn n ṣiṣẹ daadaa ko too di pe o ku.

O ni oun ko ṣayẹwo kankan si ẹjẹ to wa lara aṣọ-bẹẹdi naa lati le fidi rẹ mulẹ pe loootọ ẹjẹ eeyan ni tabi bẹẹ kọ.

Leave a Reply