Iwadii n lọ lori olukọ ti wọn lo fẹẹ fipa ba akẹkọọ lo pọ ni Fasiti Ifẹ-Awọn Alaṣẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn alaṣẹ Fasiti Ifẹ ti sọ pe awọn ko ni i faaye gba iwa fifi ibasun gba maaki latọdọ olukọ kankan bo tilẹ wu ko ga to.
Ọrọ idaniloju yii jade latari ẹsun fifi ibalopọ dunkooko mọ awọn akẹkọọ eyi, ti wọn fi kan Ọjọgbọn Joseph Ọpẹfeyitimi to wa ni ẹka Linguistics and African Languages, nile ẹkọ naa.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileewe naa, Abiọdun Ọlanrewaju, fi sita laipẹ yii lo ti ṣalaye pe akẹkọọ ti ọrọ naa kan, Boluwatifẹ Hannah Bababunmi, lo kọ iwe ifẹhonu han si awọn alaṣẹ, o ni ṣe ni Ọjọgbọn naa fẹẹ fipa ba oun lajọṣepọ ninu ọfiisi rẹ.
Ọlanrewaju ni awọn alaṣẹ ti gbe igbesẹ lori lẹta naa yatọ si ahesọ to n lọ kaakiri pe awọn n fi ọrọ naa falẹ.
O ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022, ọjọ kọkanlelogun si ni Boluwatifẹ kọ lẹta si awọn alaṣẹ.
“Gẹgẹ bi a ṣe maa n ṣe, awọn igbimọ ni ẹka ti ọjọgbọn yii wa kọkọ jokoo lori ọrọ naa, lẹyin iwadii wọn, wọn fidi rẹ mulẹ pe Ọjọgbọn Ọpẹfeyitimi ni nnkan kan ṣe ninu ẹsun naa.
“Ipele keji ni awọn Fakọọti rẹ, iyẹn ẹka to ti n ṣiṣẹ, ẹni to si jẹ alakooso wọn, Ọjọgbọn Niyi Okunoye, taari ọrọ naa si awọn igbimọ ti ileewe gbe kalẹ lati gbogun ti iwa ifipabanilopọ tabi fifi ibasun dunkooko mọ akẹkọọ nitori maaki.
“Nigba ti awọn yẹn naa jokoo, wọn paṣẹ pe ki Ọjọgbọn Ọpẹfeyitimi koju ijiya to ba tọ lori ẹsun naa. Lẹyin naa ni awọn alakooso Fasiti yoo gbe abọ ohun ti igbimọ naa sọ fun awọn igbimọ oluṣakoso Fasiti Ifẹ jade, nitori ohun ti awọn yẹn ba sọ ni abẹ ge.
“A fẹẹ fi awọn araalu lọkan balẹ pe a ki i fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iwa ibajẹ labẹ bo ti wu ko ri, bẹẹ ni a maa tẹsiwaju lati daabo bo ẹtọ awọn akẹkọọ wa, paapaa, awọn obinrin.
“O ti di awọn olukọ mẹta ti fasiti yii ti le danu lori awọn ẹsun iru eleyii, akọkọ wa lati ẹka iṣiro owo, ekeji lati ẹka imọ ede oyinbo ati ẹkẹta lati ẹka ti wọn ti n kọ nipa ibaṣẹpọ kaakiri agbaye.”

Leave a Reply