Iwọde ifẹhonuhan: Awọn oluwọde jọsin nita gbangba lọjọ Sannde ni Plateau

Adewale Adeoye

Ọna ara lawọn araalu Jos, nipinlẹ Plateau, gbe iwọde ita gbangba wọn gba lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ yii. Bawọn kan ti wọn jẹ ẹlẹsin igbagbọ ṣe ko ara wọn jọ sẹgbẹẹ kan loju titi, ti wọn n ṣe isin aarọ, bẹẹ lawọn kan ti wọn jẹ Musulumi bẹrẹ si i ṣe asalatu tiwọn lẹgbẹẹ kan naa. Lara awọn gbajumo ti wọn wa nibi iwọde naa ni ojiṣẹ Ọlọrun kan, Prophet Isa El-Buba, ati Solomon Dalung, to ti figba kan jẹ minisita fun ere idaraya lasiko ijọba Buhari wa.

Ṣe ni wọn di ikorita oju ọna marosẹ Old-Airport, to wa niluu Jos, pa patapata, ti wọn si ni ki awọn mọto maa lọọ gba adugbo mi-in kọja ni gbogbo asiko ti wọn fi wa nibẹ.

Wọn ni o ṣe pataki pupọ fawọn lati ke si Ọlọrun Ọba bayii lati waa gba akoso ijọba orileede Naijiria lọwọ awọn olori wa bayii. Wọn fi kun un pe ohun ti awọn n gbafura fun bayii ni pe ki nnkan yipada si daadaa fawọn araalu ni kiakia bayii.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjo kin-in-ni, oṣu yii, lawọn ọmọ orileede yii ti n ṣewọde ifẹhonuhan lati fi sọ funjọba orileede yii pe ilu le, ko si owo, ko si ounjẹ, epo wọn, ohun gbogbo si gbowo lori kọja sisọ.

Awọn eeyan ilu Jos naa wa lara awọn to n ṣewọde ifẹhonuhan yii. Ṣugbọn wọn gbe e gba ọna mi-in lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, pẹlu bi awọn oluwọde naa ko ṣe lọ si ileejọsin koowa wọn lati lọọ ṣe isin, to jẹ pe niṣe ni gbogbo wọn paro jọ si oju kan naa, ti wọn si n gbadura si Ọlọrun lori ọrọ Naijiria nibẹ.

Leave a Reply