Iwọde nla yoo waye l’Abẹokuta lọjọ Aje

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ohun to daju ni pe iwọde nla leyi ti awọn ọdọ ilu Abẹokuta fẹẹ ṣe lọla ode yii, iyẹn Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa yii, ‘Abeokuta  Mega Protest’ ni wọn pe e.

Nibi ti iwọde ọhun maa lagbara de, wọn lawọn yoo ti gbogbo Abẹokuta pa ni o (Total Lockdown) ni wọn pe e.

Fẹẹrẹ, laago mẹfa idaji, niwọde ifẹhonu han naa yoo bẹrẹ, aago mẹfa irọlẹ ni wọn lawọn yoo pari ẹ. NNPC, l’Oke-Mosan, ni wọn ti fẹẹ gbera.

Ki si lohun ti wọn fẹẹ tori ẹ ṣewọde ti wọn pe ni ‘Operation sọrọ soke yii’, wọn ni nitori awọn ọlọpaa afiyajẹ alaiṣẹ naa ni, nitori idajọ ododo ti ko si ni Naijiria, nitori ijọba ti ko daa to wa ni Naijiria, nitori ai si ifọkanbalẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Jijẹ mimu wa daadaa gẹgẹ bi atẹjade to n polongo iwọde yii ṣe wi, koda, wọn ni beeyan ba fẹẹ di lọ sile, aaye wa.

Leave a Reply