Iwọde ominira Yoruba la maa fi ‘June 12’ ṣe-Sunday Igboho

Ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho, ti kede pe iwọde fun bibeere fun Orileede Yoruba lawọn yoo fi ọjọ ti ijọba ya sọtọ gẹgẹ bii ọjọ ayajọ ijọba awa-ara-wa, June 12, ṣe. Bẹẹ lo rọ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lati ma ṣe di awọn to ba jade fun iwọde naa lọwọ.

Igboho sọrọ yii latẹnu agbẹnusọ rẹ lori eto iroyin, Ọlayẹmi Koiki, ninu fideo kan to n ja ran-in lori ẹrọ ayelujara. O ni kaakiri ilẹ Yoruba ni iwọde yii yoo ti waye ni Satide, ọjọ kejila, oṣu yii.

Igboho ni, ‘A n lo asiko yii lati ke si ijọba Buhari pe ki wọn ma ṣe ṣe akọlu si ẹnikẹni, ki wọn si ma ṣe jẹ ki itajẹsilẹ waye, nitori bi ohunkohun ba ṣẹlẹ, yoo le gidi gan-an ni.’ Bẹẹ lo ni gbogbo ohun to n lọ ni awọn ajọ agbaye yoo ri.

O fi kun un pe awọn ti ṣetan lati gba ohun to jẹ ẹtọ awọn.

Leave a Reply