Iwọde SARS: Buhari n ko awọn ṣọja bọ o

*Ṣugbọn awọn ọdọ ni ihalẹ lasan ni

Aya awọn eeyan ti n ja bayii o, paapaa awọn araalu ti wọn gbọ ikede lẹnu olori awọn ṣọja labẹ ijọba Buhari yii, Tukur Burutai, lọjọ Satide to kọja pe awọn yoo ko awọn ọmọ ogun ilẹ, iyẹn awọn ṣọja, kaakiri Naijiria, paapaa ni ilẹ Ibo ati ilẹ Yoruba, fun igbaradi kan ti wọn fẹẹ ṣe. Eleyii ti wọn ni awọn fẹẹ ṣe yii, Operation Crocodile Smile (Ẹrin ahanrinhan) ni wọn pe e. Ọga awọn ṣọja pata yii ṣalaye ọrọ naa pe bi awọn ti ṣe maa n ṣe niyẹn, asiko si ti tun to fun awọn ṣọja naa lati jade. Ṣugbọn bo ti sọrọ naa, gbogbo awọn ọlọgbọn ati amoye ilu ti wọn gbọ ọrọ naa ni wọn kun hun-un hun-un, wọn ni Buhari atawọn eeyan rẹ n bakan bọ, pe ki i ṣe nitori awọn ṣọja kankan fẹẹ ṣegbaradi ni wọn ṣe fẹẹ rọ wọn da sita, nitori awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde SARS ni wọn yoo ṣe ko wọn jade wa, wọn fẹẹ waa fi wọn dẹruba wọn, tabi pa wọn ni.

Awọn eeyan nla nla niluu ni wọn ti kigbe bẹẹ, Fẹmi Falana, Fẹmi Fani-Kayọde, Ẹgbẹ Afẹnifẹre, awọn ẹgbẹ ajijagbara loriṣiiriṣii, gbogbo wọn ṣaa n sọ pe kinni yii ko daa ni. Eyi to tilẹ ya awọn eeyan lẹnu diẹ ni ti Apapọ Ẹgbẹ awọn Ọdọ nilẹ Hausa, Northern Coalition Group, ti wọn tẹ atẹjade pe ki ijọba yii ma dan idankuudan kankan wo, ki wọn ma sọ pe awọn n ko awọn ṣọja kan jade fun igbaradi, nigba to ṣe pawọn ṣọja ti wọn ba ko jade yii yoo maa rin oju titi ati oju ọna kiri ni, ti wọn si mọ pe awọn ọdọ ti wọn n fi ẹhonu wọn han ti wa loju ọna yii tipẹ, ti wọn ko si ba ẹnikẹni ja, ti wọn ko si di ẹnikẹni lọwọ, tabi kọ lu agbofinro kankan. Ṣugbọn bi awọn ṣọja yii ba jade, ti wọn ba n gba ọna kan naa ti awọn to n fi ẹhonu wọn han lori SARS yii wa, bawo ni wọn ko ṣe ni i kọ lu ara wọn.

Awọn apapọ ẹgbẹ Ọdọ nilẹ Hausa yii tilẹ ni amọran to dara fun Buhari ati awọn ọga ṣọja, wọn ni bi wọn ba mọ pe o di dandan ki wọn ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe yii, ko si ibi meji to dara ju lọ lati lọọ ṣe e ju inu aginju, tabi itosi aginju Sambiza, nibi ti awọn Boko Haram ti n daamu ilu lati ọdun yii wa. Abdulazeez Sulaiman ni akọwe awọn ẹgbẹ yii, oun lo si gbe iwe wọn jade, to ni ohun ti awọn pinnu nipade awọn niyẹn. O tiẹ ni awọn ti fiwe naa ranṣẹ si Buhari atijọba rẹ, pẹlu awọn olori ṣọja gbogbo, pe ki yoo si ohun to dara ju lasiko yii ju ki awọn ṣọja lọọ maa ṣe igbaradi wọn nitosi aginju Sambisa lọ, ati ni awọn agbegbe ilẹ Hausa, nibi ti awọn janduku ti fi ṣe ile wọn. Idi ni pe bi awọn janduku yii ba ti le ko firi awọn ṣọja wọnyi, o ṣee ṣe ki wọn sa lọ. Ṣugbọn lati ko awọn ṣọja wa si ilẹ Ibo tabi ilẹ Hausa lasiko yii ko boju mu.

Amọ ki lo de ti awọn eeyan yii ko fẹ ki wọn ko ṣọja sita bayii? Ki lo de ti ara n fu awọn eeyan yii pe ohun ti wọn fẹẹ wa fi awọn ṣọja yii ṣe ni lati fi le awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde SARS jẹẹjẹ won?  Ki lo de ti wọn ko gba ọga ṣọja, Burutai, to ni awọn ko ba ti ẹnikẹni wa, iṣẹ awọn lawọn n ṣe, gbọ? Ọrọ naa le ju bẹẹ lọ ni, iriri lo si n mu awọn eeyan yii fura pe nnkan ti ko dara le ṣẹlẹ si awọn ọdọ ti wọn n kiri wọnyi. Ohun ti wọn ti ri ni wọn ṣe n sọ pe ki ijọba apapọ ma dan an wo, ti Fẹmi Falana si ṣeleri pe ti ṣọja kan ba paayan kan ṣoṣo ninu awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde yii, oun yoo fi ẹjọ Buhari ati tawọn olori ṣọja wọnyi sun ile-ẹjọ agbaye, oun yoo pe wọn lẹjọ sibẹ, ohun ti wọn ba si ri nibẹ, ki wọn fi ara mọ ọn. Ọpọ awọn olori orilẹ-ede latijọ ati awọn olori ologun ni wọn wa lẹwọn bayii, ile-ẹjọ agbaye yii lo n sọ wọn si i.

Awọn Fẹmi Falana mọ pe ki i ṣe ohun ti ijọba atawọn ṣọja fẹẹ ṣe ni wọn n sọ jade, wọn fẹjẹ sinu, wọn n tutọ funfun jade lẹnu ni. Ohun to ṣẹlẹ lọdun mẹta sẹyin lo kọ wọn lọgbọn. Ninu oṣu kẹsan-an, ọdun 2017, awọn ọdọ ilẹ Ibo kan, labẹ orukọ ẹgbẹ wọn, IPOB, bẹrẹ iwọde kan, wọn ni awọn yoo fa wahala ti ijọba ko ba fun awọn ni ipinlẹ Biafra, Nnamdi Kanu ni olori ẹgbẹ naa. Ọrọ yii ni ijọba Buhari yii kan naa gbọ, oun ati Burutai olori ṣọja yii naa ni o, ni wọn ba ni awọn ṣọja n lọ si ilẹ Ibo fun igbaradi, orukọ ti wọn si pe igbaradi naa ni Operation Crocodile (Ẹrin ahanrihan), bii eleyi ti wọn fẹẹ ṣe yii. Ṣugbọn ko si igbaradi kan ti awọn ologun naa ṣe ju pe ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an, ọdun naa, wọn kọ lu awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB, awọn ti wọn pa danu ninu wọn o lonka, wọn si ṣe awọn obi Kanu leṣe nigba ti wọn wa a dele, ti wọn ko ba a.

Awọn ọdọ ti wọn pa nilẹ Ibo nigba naa ko ṣee fẹnu sọ, nitori niṣe lawọn ṣọja wọnyi doju kọ wọn bii ẹni to wa loju ogun, ti wọn si ṣe ọgọọrọ wọn leṣe, ti awọn mi-in si sọnu titi doni, bi wọn ku, bi wọn ye ni, ti ẹnikẹni ko le sọ titi doni yii, lẹyin ọdun mẹta. Bẹẹ awọn ṣọja naa ko sọ pe awọn n lọọ jagun nilẹ Ibo, wọn ko si sọ pe awọn n lọọ koju awọn to n pariwo Biafra, wọn kan ni awọn n lọ fun igbaradi ti awọn n ṣe yika Naijiria nigba naa ni, ati pe ilẹ Ibo lawọn ti fẹẹ bẹrẹ, ṣugbọn ko si igbaradi kan lọhun-un, wọn lọọ doju ibọn kọ awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB ni. Iru awọn ṣọja ti wọn ko lọ nigba naa, iru awọn ohun ti wọn ni wọn fẹẹ ṣe nigba naa iru wọn naa ni wọn fẹẹ ko kaakiri ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo bayii, ati ni gbogbo ibi ti awọn ọdọ ba ti n ṣe iwọde SARS, ohun tawọn eeyan si ṣe n beere ni pe ki lo de to jẹ asiko yii ni wọn fẹẹ ṣe bẹẹ.

Ohun to n ba awọn eeyan lẹru ree, ti wọn si n ṣe ikilọ fun ijọba Buhari pe ki wọn ma ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe yii, nitori bi wọn ba ṣe e, ọrọ naa le ba ibi ti awọn naa ko ro yọ si wọn. Ṣugbọn ẹru lo n ba ijọba Buhari naa, nitori awọn ohun ti wọn ti ri to ṣẹlẹ loju awọn naa, to si jẹ bi awọn kinni yii ti bẹrẹ naa ree. Bi eeyan ba ri Aarẹ ana, Ọmọwe Goodluck Ebele Jonathan, to n paara ọdọ Muhammadu Buhari bayii nile ijọba Aso Rock, ọpọ eeyan ko ni i mọ ohun to sọ wọn di ọrẹ tuntun. Buhari gbe iṣẹ kan fun Jonathan to n ṣe ni. Rogbodiyan kan lo ṣẹlẹ ni orilẹ-ede Mali, nibi ti awọn ṣọja ti gbajọba, ti wọn si le ijọba alagbada to wa nibẹ kuro, ti wọn ti olori orilẹ-ede naa mọle fun igba diẹ ki wọn too fi i silẹ, ti wọn si ni awọn yoo ṣejoba titi ti alaafia yoo fi wa lati le da ijọba pada fun awọn oloṣelu ni. Ọrọ naa ko girigiri ba awọn olori ilẹ Afrika to ku.

Ohun to jẹ ko ko ijaya ba wọ ni pe bii ere lọrọ bẹrẹ, ti awọn araalu lawọn ko fẹ ijọba to wa ni Mali yii nigba naa mọ, ti wọn n fi ẹhonu han bayii, ti wọn si n rin kaakri igboro. Nigba ti ọrọ naa fẹẹ di wahala, lẹyin ti awọn eeyan diẹ kan ti ku, ni awọn ṣọja ba bọ saarin ilu, wọn si gbajọba lọwọ olori orilẹ-ede Mali, ni wọn ba rọ oun ati awọn ti wọn ko da si atimọle. Awọn olori ijọba to ku, ni Naijiria, titi de Ghana ati awọn ilẹ West Afrika to ku ni ọrọ naa ja laya gidi, wọn si sare gbe igbimọ kan dide lati ba wọn yanju ọrọ naa, ninu igbimọ yii ni Jonathan wa gẹgẹ bii aṣoju ti Buhari fa kalẹ fun wọn. Ṣugbọn gbogbo bi wọn ṣe ṣe to naa, awọn ṣọja yii ko gba o, wọn ni afi ki awọn ṣejọba awọn, awọn naa ni wọn si n ṣejọba orile-ede Mali lọwọlọwọ, ti ko si si kinni kan ti ẹnikẹni le ri ṣe si i.

Ko too di igba naa paapaa, iṣẹlẹ kan ti waye ni ilẹ awọn Larubawa to da gbogbo nnkan ru patapata fun wọn titi doni. Arab Spring, tabi Arab Uprising (Rukerudo ilẹ Larubawa) ni wọn pe kinni naa to bẹrẹ lati ọdun 2010, to si daamu awọn orilẹ-ede Larubawa yii titi di ọdun 2015, koda titi di asiko yii paapaa, ti ọrọ naa si le ọpọlọpọ awọn olori orilẹ-ede wọn lọ. Ọpọ awọn olori orilẹ-ede nilẹ Arab ni wọn le kuro nipo, ti awọn mi-in fi iku ṣe ifa jẹ, ọrọ naa si bẹrẹ si i ran, o fẹrẹ ma si orilẹ-ede ti ko fara gba a lọdọ wọn. Bẹẹ ohun kekere lo bẹrẹ ẹ, bii ere tilẹ ni ọrọ naa bẹrẹ, afi bo ṣe di nla, ti apa ko si ka a mọ. Ohun to n ba awọn Buhari lẹru ree, pe ki iru ohun to bẹrẹ nilẹ Larubawa lọdun naa lọhun-un ma tun fo de apa ibi yii, ko ma si di pe Naijiria ni yoo ti bẹrẹ, bo ba si ṣẹlẹ ni Naijiria, awọn ti wọn n ṣejọba yii ni yoo kọkọ gbe mi.

Ohun to fa rukerudo ilẹ Arab yii, ọrọ awọn ọlọpaa ni o. Loootọ, awọn kinni kan ti wa nilẹ tẹlẹ, iwa irẹjẹ ati idaamu loriṣiiriṣii fawọn araalu, awọn eeyan si ti n wa ibi ti wọn yoo ti ba ijọba fa ijangbọn, tabi ọna ti wọn yoo fi jẹ ki ijọba ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe. Ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ko fara mọ iwa ijọba wọn, paapaa orilẹ-ede Tunisia, nibi ti wahala yii ti bẹrẹ, eyi to si n dun wọn ju ni iwa buruku ti awọn ọlọpaa ibẹ n hu. Lọjọ kan lawọn ọlọpaa yii fiya jẹ ọkunrin kan to n jẹ Mohammed Bouaziz. Baaro (Wheel barrow) ni Bouazizi yii n ti, ṣugbọn baaro to n ti yii, o fi n ta ọja pẹẹpẹẹpẹ ni, ohun to si fi n jẹun ree, ko ni iṣẹ mi-in to n ṣe, bo tilẹ jẹ pe o ti kọ ẹkọ to yẹ ko fi ri iṣẹ ṣe, nigba ti ko si ri iṣẹ, o n fi owo to ba ri ra awọn ọja wẹwẹ yii, yoo si ko wọn sinu baaro, yoo maa ti i kaakiri. Ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn pere ni.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2010, ọmọkunrin yii ya owo lọwọ awọn ara ati ọrẹ, o ni ki oun fi ra ọja, koun si da owo naa pada fun wọn. O ni oun yoo ta ọja oun tan lọjọ keji si ọjọ kẹta, oun yoo si da owo naa pada kia koun tun le ri omi-in ya. Ṣugbọn ni ọjọ kẹtadinlogun, iyẹn ọjọ keji to yawo, o ra ọja rẹ, o si bẹrẹ si i fi baaro ti i kiri, o n ta a. Ko ti i rin jinna nigba ti awọn ọlọpaa mu un, wọn ni ki lo de to n fi baaro taja kaakiri. Bouazizi ni nigba toun jade ileewe ati ile ekọṣẹ toun ko ri iṣẹ, oun yoo ṣaa ri nnkan kan ṣe funra oun. O ni ohun to jẹ koun maa fi baaro taja kiri ree o. Loootọ ni Tunisia nigba naa, ofin wọn ko faaye gba ọja loju titi, ṣugbọn ofin naa ko kan awọn ti wọn ba n fi baaro ta ọja wọn kiri. Bo ba tun waa jẹ owo wa lọwọ Bouaziz ni,  to ri owo fun awọn ọlọpaa yii, o ṣee ṣe ki ọrọ rẹ ṣẹ pẹrẹ. Ṣugbọn ko ti i taja jinna, owo ko si lọwọ rẹ.

N ni awọn ọlọpaa yii ba ki i, ni wọn na an bii ko ku, wọn si gba gbogbo ọja rẹ ati baaro rẹ, wọn rọ ọ sinu mọtọ wọn, ni wọn ba gbe e lọ. Ninu gbogbo iya to jẹ ẹ nibẹ, eyi to dun ọmọdekunrin naa ju ni pe ọlọpaa obinrin kan to jẹ ọga wọn gba oun leti, o si tun tutọ si oun lara, bẹẹ lo bu baba oun to ti ku pe ki lo de ti ko tọju oun to jẹ baaro ni oun n ti kiri. Ara Mohammed Bouazizi  gbona, inu si bi i buruku. Ṣugbọn apa rẹ ko ka awọn agbofinro to fiya jẹ ẹ yii, nitori ajẹkun iya ni ẹni to ba ta ko awọn ọlọpaa naa yoo jẹ. Ni ọmọkunrin naa ba gbera, o loun yoo de ọfiisi gomina ki oun sọ ohun to n ṣe oun ati iya ti wọn fi jẹ oun. Ni ọfiisi gomina, wọn ko jẹ ko ri gomina tabi ko tilẹ sun mọbẹ, wọn ni kin ni iru rẹ yoo ri gomina fun, tabi ti yoo laya lati sọ pe oun fẹẹ ba ọlọla ju lọ sọrọ, wọn ni ko maa lọ, bi ko ba kuro nibẹ iya gidi yoo jẹ ẹ.

Nibẹ naa ni ọmọkunrin yii ti n sọ fun wọn pe oun yoo pa ara oun si wọn lọrun o, nitori ko sohun toun yoo maa jẹ toun ba wa laye, bẹẹ ni ko si iṣẹ ti oun yoo maa ṣe. Ṣugbọn ẹrin ni awọn ọlọpaa ati awọn ti wọn wa ni ẹnu ọna ọdọ gomina n fi i rin. N lo ba bọ sita, o si lọ siwaju diẹ, o ra epo bẹntiroolu sinu koroba kan, o si pada siwaju ọọfiisi gomina naa, nibẹ lo ti duro niwaju awọn mọto to n lọ, to si pariwo pe, ‘Ko si ohun ti mo maa maa jẹ! Ẹ ti di ọna ijẹ mọ mi, ẹ tun fiya jẹ mi, a o pade niwaju Oluwa o!’ Lẹyin to si ti da epo galọọnu kan naa kari gbogbo ara rẹ, o ṣana sira rẹ lara, ina naa si bẹrẹ si i jo o, o si wa ninu ina naa lai sunkun. Ko si ẹni to le tete sun mọ ọn, nigba ti awọn to ni ẹrọ ipana yoo si fi de ọdọ rẹ, o ti jo kọja idaji ara. Wọn sare gbe e lọ si ọsibitu digbadigba,  ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, nitori ni ọjọ kẹrin, oṣu kin-in-ni, ọdun 2011, ọkurin naa dagbere faye.

Lati ọjọ to ti sun ara rẹ ni iwọde ti bẹrẹ, lati ọjọ naa lawọn ọdọ ti bẹrẹ si i ṣe iwọde, wọn ko si sinmi titi di ọjọ ti wọn sinku ẹ. Awọn ọlọpaa ati ijọba ro pe wọn yoo ṣe iwọde diẹ, wọn yoo sinmi ni, ṣugbọn ko ri bẹẹ, laarin meji ni wọn si yi iwọde naa pada, ti wọn bẹrẹ si i sọ pe afi ki aarẹ to wa lori oye naa kuro, awọn ko fẹ ẹ mọ. Ere ni, awada ni, ọrọ naa lo le aarẹ Tunisia igba naa kuro lori oye, bẹẹ ni iṣẹlẹ naa ran de Libya ati awọn ilẹ Arab to ku, nibi ti awọn ọdọ ti n jade lojoojumọ pe afi ki ijọba awọn lọ. Ko si ọna ti awọn ijọba yii ko gba lati dena de awọn ọdọ yii, tabi lati ya wọn, tabi lati da ija silẹ laarin wọn, ṣugbọn ko ṣee ṣe, nitori lojoojumọ ni wọn pọ si i, ojoojumọ ni awọn kan si n dide lati ran wọn lọwọ. Bẹẹ ni wọn ṣe bii ere bii ere ti wọn sọ ọrọ naa di rannto, ti wọn si le awọn olori ijọba pupọ lọ.

Iru nnkan to n ba awọn Buhari lẹru niyi, idi si niyẹn ti wọn fi fẹẹ ko ṣọja jade. Ko too kan awọn ṣọja bayii, wọn ti kọkọ wa ọna lati fi awọn janduku le awọn eeyan naa, ti wọn fi awọn tọọgi le wọn, ṣugbọn ti awọn yẹn kapa wọn. Wọn ti gbiyanju lati da awọn tọọgi si aarin wọn ki wọn da wahala silẹ, ki wọn si le sọ pe awọn ọdọ naa lo bẹrẹ wahala, ati pe wahala ti wọn n ṣe le da ilu ru, ṣugbọn awọn ọdọ naa yọ awọn tọọgi ti wọn ran wa kuro laarin wọn, wọn le wọn lọ. Nigba ati wọn ṣe eleyii ti ko to wọn, wọn sare pe awọn olukọ yunifasiti ti wọn ti n ba ja lati ọjọ yii wa, ti awọn olukọ naa si ti daṣẹ silẹ, wọn ni ki wọn tete maa bọ, awọn yoo ṣe gbogbo ohun ti wọn ba fẹ fun wọn, ki wọn pada si ileewe, ki wọn si maa ba iṣẹ wọn lọ. Ohun ti wọn ṣe ṣe eleyii ni pe bi awọn tiṣa yunifasiti yii ba pada si ile-ẹkọ, awọn ọdọ naa yoo dinku loju titi, nitori wọn yoo gba ileewe wọn lọ.

Ṣugbọn awọn olukọ yii naa gbọn, wọn ni ki ijọba ma fi ẹnu ṣalaye ọrọ fawọn rara, ki wọn kọwe gbogbo adehun ti wọn wi yii jade, ki wọn si san asansilẹ owo ti wọn fẹẹ fun awọn. Nigba tiyẹn naa ko fẹẹ tete ṣiṣẹ, wọn ni ki awọn agunbanirọ, NYSC, tete maa lọ si kampu, ni ibudo wọn, ki wọn le lọọ bẹrẹ iṣẹ, iyẹn naa ko jọ pe yoo ṣiṣẹ. Idi eyi ni wọn ṣe ro o paapaapa pe ki awọn kuku gbe awọn ṣọja jade. Awọn kan ti gbiyanju lati sọ iwọde naa di ti Yoruba ati Ibo, ki wọn le ni ilẹ Yoruba nikan lo ti n ṣẹlẹ, ṣugbọn bi a ti n kọroyin yii, wọn ti gbegi di ọna to lọ si papa-ọkọ ofurufu ilu Abuja, debii pe yoo ṣoro ki ẹnikẹni too wọle tabi jade, bẹẹ ni iṣoro wa gan-an fun ijọba yii lati ṣe ofin pe awọn ọdọ naa ko gbọdọ ṣe iwọde, nitori ọrọ naa ti di ti gbogbo aye, debii pe bi wọn ti n ṣe iwọde yii ni Naijiria ni wọn n ṣe e ni awọn ilu ọba kaakiri.

Gbogbo ohun to n mu ijọba ronu ṣọja naa ree, ṣugbọn gbogbo aye lo ni wọn ko gbọdọ lo ṣọja fi le awọn ọmọ naa, ati pe ti kinni kan ba ṣe wọn, ijọba Buhari yoo fara ko o. Ọrọ naa wa bo ṣe wa, o duro soju kan, aṣa ti awọn ọmọ yii si n da laarin ara wọn bayii ni ‘Sọrọ soke’,  ariwo olori ijọba ni wọn si n pa, ti wọn n sọ pe ‘Buhari, sọrọ soke!

Leave a Reply