Iwọde SARS l’Ekoo: Awọn ṣọja binu si Sanwo-Olu patapata!

Ademọla Adejare

Bi Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ba mọ pe bi ọrọ igbimọ ti oun gbe dide yoo ti pada ja si niyi, boya ni yoo gbe igbimọ kankan dide lori iwọde SARS to ṣẹlẹ loṣu to kọja, niṣe ni iba dakẹ jẹẹjẹ bii omi adagun. Ṣugbọn nitori ko jọ pe ọrọ naa ye gomina yii lati ibẹrẹ, o si ti ro pe ohun ti wọn le fi eto ati ọgbọn ijọba bo gbogbo ohun to ṣẹlẹ mọlẹ ni, o gbe igbimọ kan dide lati wadii ohun to fa rogbodiyan iwọde SARS, ohun ti awọn ọdọ n fẹ ati ohun ti awọn le ṣe. Igbimọ yii ti waa di nnkan mi-in si i lọrun bayii ṣaa o, nitori awọn aṣiri to n tu niwaju igbimọ naa lojoojumọ ti sọ Sanwo-Olu ati awọn ṣọja di ọta ara wọn, boya ni ajọṣẹ gidi kan yoo ti aarin wọn jade mọ, nitori bi awọn ṣọja ṣe n binu si ọkunrin gomina yii, bẹẹ ni gomina naa n binu si wọn. Ṣugbọn apa gomina ko ka ṣọja, nitori ko si ohun ti oromọdiẹ yoo fi ẹyẹ aṣa ṣe.

Awọn ṣọja n binu, wọn ni Sanwo-Olu purọ mọ awọn ni gbangba, o doju ti awọn pe oun ko mọ bi awọn ṣe de too-geeti ni Lẹkki, bẹẹ oun lo ranṣẹ pe awọn. Sanwo-Olu naa n binu pe ọrọ yii, ọrọ awo ni, ki i ṣe ohun to yẹ ko lu jade rara, bawo lawọn olori ologun yoo ṣe waa maa tu aṣiri ohun ti awo ṣe. Ṣugbọn awọn ologun ti wọn jade mọ ohun ti wọn n ṣe, wọn mọ pe bi ọrọ naa ti ri yii, bi awọn ko ba jade sọrọ soke, to ba di lọjọ iwaju, ti awọn ile-ẹjọ agbaye ba ko iwe aṣiṣe tawọn ṣe kalẹ fawọn, ati Buhari ati awọn olori ṣọja pata, gbogbo wọn le fara gba a, ti wọn yoo dero ẹwọn, iyẹn bi ile-ẹjọ agbaye yii ko ba ni ki wọn yẹgi fun wọn, nitori pe wọn mọ bi awọn ṣọja kan ti yinbọn pa awọn eeyan ti wọn ṣewọde, awọn ti wọn ko mu ohun ija dani, ti wọn ko si fajangbọn, to jẹ nibi ti wọn jokoo si jẹẹjẹ lawọn ṣọja ti lọọ bawọn.

Ọrọ ti burẹkẹ bayii ṣaa o, awọn ṣọja ti jade wa siwaju igbimọ, wọn ti ṣalaye ọrọ, kaluku si ti mọ ohun ti wọn jọ se ti ile fi jona. Ṣugbọn awọn aṣiri kan ṣi wa ti ko ti i tu sita tan. Bo tilẹ jẹ awọn ṣọja yii gba pe awọn wa nibẹ, awọn lọ si too-geeti ni Lẹkki lati tu awọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde naa ka, sibẹ lojoojumọ lawọn ṣọja yii n ta ku pe awọn kọ lawọn yinbọn nibi iṣẹlẹ naa, ati pe ẹnikẹni ko ku nibẹ. Bẹẹ gomina Sanwo-Olu funra ẹ ti gba pe oun ri oku meji, oun si de ọsibitu funra oun lati ri ọpọlọpọ awọn ti ibọn ba nibi oju ija yii, o si sọ fawọn oniroyin pe gẹgẹ bii fidio ti oun ri, awọn ṣọja lo yinbọn. Yatọ si eyi, girangiran ni awọn ọta ibọn kun ibi ti wọn ti da gbogbo ẹ ru ni too-geeti yii, awọn onimọ si ti ni ọta ibọn naa ki i ṣe tawọn ọdaran, o jọ tawọn ologun Naijiria daadaa. Ta lo waa yinbọn o, eeyan meloo lo si ku? Ta lo pa wọn? Lara awọn iṣoro to wa niwaju igbimọ yii niyẹn.

Yoo ṣoro ki ọrọ yii too niyanju pata o. Ohun to mu ki ọrọ naa yanju de ibi to de yii ni pe ki i ṣe lẹyin ti wọn fa wahala ni Lẹkki ni ijọba ipinlẹ Eko gbe igbimọ dide. Nigba togun naa ti n le, ti awọn ọdọ yii ni awọn ko gba rara mọ, ti wọn n gbegi dina ni marosẹ, ti wọn tẹdo si Lẹkki ati Sẹkiteeria ni Alausa, ti wọn ko si jẹ ki awọn onimọto lọ, nigba naa ni ijọba ipinlẹ Eko ti sare gbe igbimọ yii dide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ni wọn si ṣe ifilọlẹ igbimọ naa, ti ijọba ni ki wọn tete bẹrẹ iṣẹ wọn. Adajọ Doris Okuwobi ni wọn fi ṣe olori igbimọ naa, wọn si ko awọn meje mi-in ti i, wọn ni ki wọn fi oṣu mẹfa ṣe iṣẹ wọn. Ijọba ni oun fẹẹ mọ ohun to n bi awọn ọdọ yii ninu lori ọrọ SARS, oun fẹ ki awọn ọdọ mu amọran wa lori ohun ti ijọba yoo ṣe ti iru iwọde bayii ko fi ni i waye mọ, oun si fẹ ki kaluku jade wa ki wọn waa sọ ohun ti awọn ọlọpaa SARS yii ṣe fawọn gan-an.

Afi bii ẹni pe ọrọ naa daru mọ ijọba Sanwo-Olu funra ẹ loju, nitori lọjọ keji to gbe igbimọ yii dide, ọjọ naa jẹ ogunjọ, oṣu kẹwaa, niṣe nijọba kede lojiji pe awọn yoo bẹrẹ ofin konilegbele jake-jado ipinlẹ Eko, ati pe ofin naa yoo bẹrẹ ni deede aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa, ki kaluku tete gba ile ẹ lọ. Ọrọ naa ba awọn eeyan lojiji, nitori wọn ko ro o ti rara, awọn ti wọn si ti wa ọna kan tabi omi-in de ibi iṣẹ wọn ko mọ bi wọn yoo ṣe sare pada wa sile koo to di aago mẹrin irọlẹ ti ijọba da, nitori ni bii aago kan ọṣan ni wọn ṣe ikede naa. N lọrọ ba di girigiri, kaluku n wa ọna bi yoo ti ṣe dele. Nirọlẹ ọjọ naa, ni bii aago mẹfa aabọ si meje lalẹ ni awọn ṣọja de si Lẹkki. Bi wọn si ti debẹ ni iro ibọn bẹrẹ si i ṣẹlẹ, ni ọrọ ba di bo o lọ o ya, oku bẹrẹ si i sun kaakiri.

Lẹyin ti wọn ti da wahala silẹ ni ọjọ yii, ọrọ naa fẹju si i lọjọ keji, awọn ọdọ kan binu, wọn dana sun awọn ile ati ileeṣẹ awọn eeyan ti wọn ro pe wọn lọwọ si idaamu awọn, ati awọn oloṣelu kọọkan, nigba naa ni awọn janduku si yi wọ aarin wọn, ti wọn gba ọrọ naa kanri, awọn si lo iṣẹlẹ naa lati fi da wahala silẹ ati lati fi jale kaakiri. Nigba ti wọn yoo fi pana ọrọ naa, nnkan ti bajẹ kọja kekere. Eyi mu ki iṣẹ igbimọ ti Sanwo-Olu gbe dide yii ya kiakia, nitori wọn ko duro mọ, wọn bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ ni. Ohun to si fa eyi ko ju pe ijọba fẹẹ fi han gbogbo aye pe awọn ti mura si ọrọ naa, awọn si ti fẹẹ wadii ohun to ṣẹlẹ, pe ki kaluku fọkanbalẹ, awọn yoo ridii okodoro.Ni bii ọjọ kẹrin iṣẹlẹ yii ni igbimọ naa ti jokoo, ti wọn ti ni ki awọn eeyan maa mu ẹri wọn wa, nitori iṣẹ ti bẹrẹ loju mejeeji niyẹn.

Ko too digba yii, Sanwo-Olu ti jade to ni oun kọ loun ran awọn ṣọja niṣẹ, oun ko tilẹ mọ kinni kan nipa ẹ, awọn to lagbara ju oun lọ lo wa nidii ọrọ naa o. Ileeeṣẹ ologun paapaa sare jade, awọn naa ni awọn ko mọ kinni kan nipa ẹ o, awọn ko tilẹ debẹ rara, iṣẹ awọn lawọn n ṣe ni baraaki awọn, ko sẹni to mọ ohun to ṣẹlẹ ni Lẹkki. Ṣugbọn nigba ti ọmọbinrin oṣere kan, Obianuju Udeh (DJ Switch) jade pẹlu fidio tirẹ, to fi awọn ṣọja han nibi iṣẹlẹ naa ni gbogbo igba ti ibọn n ro, to fawọn ṣọja han nibi ti wọn ti n sare kiri ati nibi ti awọn eeyan ti n gbe oku to ku, to si ṣalaye pe oun ri awọn ṣọja ti wọn n ko awọn oku sinu mọto wọn, ti ileeṣẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan agbaye, Amnesty International, si tu aṣiri bi awọn ṣọja ṣe rin lati Bonny Camp l’Ekoo de too-geeti Lẹkki, awọn ologun naa ri i pe aṣiri ti tu patapata.

Ohun to jẹ ki awọn jẹwọ niyẹn o, ki i ṣe pe wọn fẹẹ jẹwọ tẹlẹ. Nigba ti fidio ọmọbinrin yii jade, wọn wa a titi ki wọn mu un, wọn le e kirakira, ṣugbọn wọn ko ri i, nitori ọmọbinrin ohun ti ra mọ wọn loju ki wọn too mọ ijamba to ṣe fun wọn. Ibinu ọrọ yii, ati alaye ti Sanwo-Olu funra ẹ ṣe pe awọn ṣọja lo yinbọn ninu fidio, oun foju ara oun ri oku meji, lo jẹ ki awọn ṣọja jade, ti wọn fi jẹwọ pe loootọ lawọn lọ sibi iṣẹlẹ Lẹkki, ṣugbọn Gomina Sanwo-Olu funra ẹ lo ranṣẹ pe awọn, ṣugbọn awọn ko yinbọn pa ẹnikẹni ni tawọn o. Bawo ni ṣọja yoo ṣe lọ sibi kan ti ko ni i yinbọn, awọn oku ti wọn si ku yii nkọ? Ta lo pa wọn, ati pe nibo lawọn oku naa wa gan-an, nitori nigba ti ilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, ko sẹni to ri oku nibi kan, bẹẹ fidio yii ṣafihan awọn oku to ku, ọmọbinrin to ya fidio naa si ṣalaye pe oun ri awọn ṣọja ti wọn n fi ọkọ gbọọrọ wọn ko awọn oku lọ. Nibi ni iṣẹ igbimọ yii ti bẹrẹ.

Nitori pe ẹri to wa niwaju wọn fi han pe ogunlọgọ awọn eeyan lo ku, ohun ti wọn kọ fẹẹ wadii ni ibi ti awọn oku naa wa, ki wọn si le mọ ibi ti wọn yoo ti ri wọn ati iru awọn eeyan ti wọn jẹ gan-an. Nibi yii ni igbimọ naa ti kọkọ ni iṣoro pẹlu awọn ṣọja, nitori ọrọ naa di wahala diẹ ki wọn too wọle si ọsibitu awọn ologun yii l’Ekoo. Ko too digba naa, awọn igbimọ yii ti kọwe si awọn ṣọja pe ki wọn waa ṣalaye niwaju igbimọ bi ọrọ ti ri, nigba to jẹ awọn naa ti jẹwọ bayii pe awọn wa ni Lẹkki, nibi ti ina ibọn ti n dahun lori awọn ọdọ ti wọn n sẹwọde. Wọn ni nibi ti ọrọ de duro naa, afi ki awọn ṣọja yii jade wa lati sọ tẹnu wọn, ki wọn waa ṣalaye bo ti jẹ ijọba ipinlẹ Eko lo pe wọn, ki wọn si sọ ohun ti wọn ṣe gan-an. N lawọn ṣọja ba yari, wọn ni awọn ko ni i jẹ iru ipe bẹẹ, pe awọn ko ni i yọju sigbimọ kan.

Alaye ti Niyi Ọṣọba, Alukoro fun ileeṣẹ awọn ologun ọwọ kọkanlelọgorin (81 Division) ti ọrọ yii kan ṣe ni pe awọn ko ni kinni kan ti awọn fẹẹ ṣe niwaju igbimọ, nitori ki i ṣe igbimọ lo ran awọn niṣẹ. Wọn ni ijọba Eko lo ran awọn, awọn ni wọn pe awọn ki awọn waa ba wọn le awọn ọdọ to n da ilu laamu naa kuro nibi ti wọn wa, bo ba si waa di pe ọrọ ti dewaju igbimọ, ijọba Eko to ran awọn niṣẹ naa ni yoo pada waa pe awọn pe ki awọn yọju sibẹ, lẹta ni wọn si gbọdo kọ. O jọ pe lẹyin tawọn ṣọja sọrọ yii, lẹta jade sọwọ awọn ọga wọn loootọ lati ọdọ ịjọba, n lawọn ṣọja yii ba gba lati yọju siwaju igbimọ, wọn lawọn n bọ waa sọ tẹnu awọn naa, ko too di pe wọn parọ ti ki i ṣe tawọn mọ awọn. Nigba to si di ọjọ keje, oṣu kọkanla, ti a wa yii, awọn ọga ṣọja lati 81 Division yii yọju siwaju igbimọ to n wadii iṣẹlẹ SARS.

Awọn mẹrin ni wọn yọju lọjọ naa, awọn ti 65 Batallion lo wa sibẹ, nitori awọn gan-an ni wọn ni wọn lọ sibi iṣẹlẹ naa. Awọn naa kọwe tiwọn dani, ẹni to si ṣaaju wọn, Musa Etsu-Ndagi, sọ pe Gomina Sanwo-Olu gan-an lo pe oun ni bii aago meje aabọ alẹ ọjọ naa, to ni awọn ṣọja n yinbọn ni Lẹkki. O ni gomina kan sọ foun pe ọga ṣọja kan ti wọn pe ni Bello lati 65 Batallion ni Bonny Camp lo wa nidii ọrọ yii o,  oun lo ṣaaju awọn to n yinbọn. Etsu-Ndagi ni lẹsẹkẹsẹ loun ti pe Bello, ti oun si beere pe ki lo de to n yinbọn ni too-geeti. O ni niṣe ni Bello kọ ‘haa’, to ni awọn ko ma yinbọn lu ẹnikẹni o, ofurufu lawọn n yinbọn awọn si. Niwaju igbimọ yii naa, wọn pe Bello funra ẹ ko waa sọrọ, n loun naa ba sọ pe ki wọn ma da awọn ti wọn n gbe rumọọsi (ahesọ) kiri lohun, o ni loootọ lawọn wa ni Lẹkki yii, ṣugbọn awọn ko yinbọn lu ẹnikẹni.

Nigba ti Bello yoo kuku tilẹ fa ọrọ naa ya, o ni inu awọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde naa dun gan-an nigba ti wọn ri awọn ṣọja ti wọn debẹ. “Ẹ wo o, nigba ti a debẹ, niṣe ni inu awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde naa n dun ṣinkin, emi funra mi ni mo si n fun wọn ni piọwọta ti wọn n mu. Mo n bẹ wọn ni, pe ki gbogbo wọn waa maa lọ sile nitori kọfiu ti ijọba ti ṣe, gbogbo wọn si gba si mi lẹnu, wọn n lọ sile wọn wọọrọ. Afi bi awọn janduku kan ṣe bẹ de, ti wọn da wahala bolẹ, ti wọn fẹẹ maa ṣe awọn eeyan leṣe. Nibi ti a ti mura lati gba awọn eeyan naa silẹ ree. Bi ọrọ naa si ti le to, awa ko yinbọn kankan lu ẹni kan o, gbogbo ibọn ti a n yin, oke ni a n yin in si, ka fi le le awọn janduku naa lọ ni! Ko si ootọ ninu awọn ti wọn n gbe ọrọ kiri pe awọn ri oku, tabi pe awa n fi mọto wa ko awọn oku. Wọn n fiyẹn ba wa jẹ lasan ni!”

Bayii ni awọn yii rojọ lọjọ naa ti wọn si ba tiwọn lọ. Ṣugbọn ẹjọ naa ri bakan loju awọn ti wọn n gbọ o, nitori ọrọ ti wọn sọ yatọ pata si ohun ti awọn eeyan ti ri lori fidio, ati bi wọn ti ri awọn ṣọja nibẹ ti wọn n le awọn eeyan kiri, ti iro ibọn si n dun lakọlakọ. Nitori ẹ lawọn igbimọ naa ṣe ni awọn ṣi n reti awọn ọga ṣọja mi-in si i, nitori ọrọ naa ko ti i debi ti awọn ti le ri gbogbo okodoro ti awọn n wa kiri. Eyi lo si ṣẹlẹ lọjọ Satide to lọ yii, nigba ti awọn ọga ṣọja wa lati 81 Division, lọjọ naa ni gbẹgẹdẹ gbina taara, aṣiri ọrọ si jade ju ti tẹlẹ lọ. Birigedia Ahmed Taiwo lo ṣaaju wọn wa, oun naa si ba awọn ọmọ igbimọ naa ti wọn duro sẹpẹsẹpẹ. Ko pẹ ti wọn de ti wọn fi bẹrẹ si i tu kẹkẹ ọrọ, bo si tilẹ jẹ pe ọrọ rẹ naa ko fi bẹẹ yatọ si ti awọn ti wọn sọrọ tẹlẹ, to si ko ijọba Eko siyọnu, agaga Gomina Sanwo-Olu.

Ọgagun Taiwo ni ki oun sọ tootọ fun gbogbo awọn ti wọn jokoo, inu awọn olori ṣọja ko dun rara si Gomina Sanwo-Olu. O ni ohun to si n bi awọn ọga yii ninu ni pe Sanwo-Olu purọ mọ awọn ni gbangba, o si sẹ awọn loju gbogbo aye. Taiwo ni ko sohun ti i ba kan awọn ninu ọrọ yii bi ko ba jẹ gomina naa ko ranṣẹ pe awọn ni. O ni ki gbogbo awọn ti wọn jokoo gbọ, ko si ohun to buru ninu ki nnkan ṣẹlẹ ki gomina ranṣẹ pe awọn alaabo to ba mọ pe wọn le yanju ọrọ naa kiakia, nitori bẹẹ, ohun to yẹ ki Sanwo-Olu ṣe naa lo ṣe yẹn. Ṣugbọn lati waa maa purọ ni gbangba pe ko sẹni to ran awọn ṣọja niṣẹ, oun ko mọ bi wọn ti debẹ, oga awọn ṣọja naa ni ọrọ naa fa ibinu yọ fawọn gan-an ni. N lo ba bẹrẹ si i ṣalaye bi ọrọ naa ti jẹ nikọọkan, ati bi kinni naa ṣe kan awọn ṣọja to wa nibẹ, iyẹn ni Bonny Camp.

O ni nigba ti wahala ọrọ yii bẹrẹ si i fẹju, ẹni ti Sanwo-Olu gbiyanju lati ri ba sọrọ ni Aarẹ Muhammadu Buhari, ṣugbọn ko tete ri i ba sọrọ nigba naa, nigba ti ipa rẹ lori igbiyanju naa si pin lo lọọ ba olori awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ Aarẹ sọrọ, to sọ ohun to n lọ l’Ekoo fun un. Iyẹn ni ko ni suuru foun, oun yoo fun un lesi laipẹ, ṣugbọn ko jọ pe o ri esi gidi mu wa lasiko, ohun to jẹ ki Sanwo-Olu funra ẹ pe ọga awọn ṣọja pata niyẹn, iyẹn Burutai. Taiwo loun mọ daadaa pe Sanwo-Olu ti pe Buratai ko too di pe o tilẹ ba awọn sọrọ rara. O ni nigba ti awọn gba ipe gomina yii, ti awọn si mura lati ba a ṣe ohun to bẹ awọn, ko si awọn ṣọja ti awọn yoo lo nilẹ, funra olori awọn ologun yii, iyẹn Buratai, lo faṣẹ si i pe ki awọn lọọ ko awọn ọmọọṣe ologun kan ti wọn wa ni ileewe ẹkọṣẹ ologun, pe ki wọn lọọ yanju ọrọ naa.

Lorọ kan, gẹgẹ bii Ọgagun Taiwo yii ti wi, ki i ṣe awọn ṣọja ti wọn ti n ṣiṣẹ tẹlẹ ni wọn ko lọ sibẹ, awọn ọmọ ẹkọṣe ologun ni. O ni iyẹn lo fa a ti awọn ko fi ko ọta sinu ibọn wọn, ti awọn kan sọ fun wọn pe ki wọn maa yinbọn soke lasan, ki wọn le fi le awọn eeyan naa lọ nibẹ ni. Taiwo ni ohun to dun awọn ju ni pe Sanwo-Olu tun ni oun ri awọn eeyan to ku, bẹẹ awọn meji to ku yii, ẹni kan ti wọn ri ni ọna Admiralty Way, ni bii maili mẹta si too-geti ni Lẹkki ni, bẹẹ ki i ṣe ọta ibọn lo pa iyẹn, wahala ni wọn lo pa a. Ẹni keji to tun ni oun ri lọsibitu to ku, ki i ṣe Lẹkki ni wọn ti gbe e wa, Yaba ni wọn ti gbe oun wa. O ni ko si ẹni to ri oku nibi kan, nitori awọn ṣọja tawọn ko yinbọn paayan, ko si si oku rẹpẹtẹ to sun ni Lẹkki. Taiwo ni ki ọrọ naa le ye gbogbo eeyan loun ṣe jade, ki wọn si mọ pe inu n bi awọn si gomina to purọ mọ awọn.

Ohun to ṣẹlẹ bayii ni pe kaka ki ọrọ naa niyanju, o tubọ n fọ loju si i ni. Gbogbo eeyan agbaye lo ri i pe oku sun ni Lẹkki; nitori awọn fidio ti wọn ri ati awọn ti kinni naa ṣẹlẹ loju wọn; awọn ṣọja ti wọn ni awọn ko debẹ tẹlẹ ti gba pe awọn debẹ bayii, ṣugbọn awọn ko yinbọn; Gomina Sanwo-Olu to sọ pe oun ko ran ṣọja niṣẹ ko sọrọ mọ lati ọjọ ti awọn yẹn ti tu aṣiri pe oun lo ran awọn; ni bayii, awọn ṣọja ti binu si gomina patapata, wọn lo purọ mọ awọn. Ta ni yoo waa ba wọn yanju ẹ? Nibo lọrọ naa yoo yọri si? Wọn wa lẹnu ẹ o!

Leave a Reply