Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ajọ TRACE ti fidi ẹ mulẹ pe iya agba kan ati ọmọ-ọmọ ẹ ni wọn jona ku patapata ninu ina to sọ laaarọ ọjọ Sannde ọsẹ yii, lagbegbe Oju-irin, ni Lafẹnwa, Abẹokuta. Bẹẹ ni ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye si ṣofo sinu ina ọhun.
Tanka kan to gbe epo lo fẹgbẹ lelẹ ni nnkan bii aago marun-un idaji ku iṣẹju mẹẹẹdogun laaarọ ọjọ Aiku naa, bo ti ṣubu ni awọn eeyan bẹrẹ si i ji epo inu ẹ to danu silẹ, bi wọn ti n gbọn epo naa pamọ ti wọn n lọ ti wọn n bọ ni ina sọ lojiji, ina ọhun lo si pada gba ẹmi awọn meji ti TRACE sọ pe wọn ku yii.
Bo tilẹ jẹ pe eeyan meji ni Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, sọ pe wọn ku, ohun tawọn kan n sọ ni pe eeyan mẹrin lo ku sinu ina yii. Wọn ni iya atọmọ pẹlu awọn meji mi-in ni.
Nigba tawọn oṣiṣẹ panapana atawọn TRACE pẹlu FRSC n ṣaajo nipa bi ina ọhun yoo ṣe ku, niṣe lawọn ọmọ ganfe kan kọ lu ọkọ awọn TRACE ati ti FRSC, ti wọn ba a jẹ.
Awọn ẹṣọ alaabo yii ba awọn to padanu eeyan wọn ati dukia sinu ina yii kẹdun, wọn si rọ awọn araalu pe ki wọn maa fọwọsowọpọ pẹlu ẹṣọ alaabo ti iru nnkan bayii ba n ṣẹlẹ lọwọ, yatọ si ki wọn maa ba mọto wọn jẹ, tabi kawọn kan maa lo asiko naa fun ole jija, wọn ni eyi buru jai, o si tabuku orilẹ-ede yii.