Iya atọmọ balẹ satimole, nitori iya ọgọta ọdun ti wọn pa l’Ojodu Abiọdun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Mary Ogbeifu, ẹni ọdun marundinlogoji (35), ati ọmọ ẹ, Godwin Ogbeifu; ẹni ọdun mẹtadinlogun (17), ti wa lọdọ awọn to n gbọ ẹsun ipaniyan nipinlẹ Ogun bayii, nitori iku iya ẹni ọgọta ọdun ( 60) ti wọn pe orukọ ẹ ni Iyabọ Ọlashẹinde, ẹni ti wọn ni iya atọmọ yii ni wọn gun un pa nile kan to wa l’Opopona Ọmọlara, Yakoyo, l’Ojodu Abiọdun, ipinlẹ Ogun.

Odi ni Godwin Ogbeifu yii, bẹẹ ni ko si tun gbọrọ pẹlu. Oun ni wọn lo kuro nile tiwọn to wa l’Opopona Akoko, Yakoyo, l’Ojodu kan naa, to lọ sile iya agba yii.

Nigba to debẹ, iya ti wọn pe orukọ ẹ ni Iyabọ Ọlashẹinde yii le e jade ninu ọgba ile naa, o loun ti kilọ fun un pe ko yee wa sile awọn mọ.

Ibinu lile ti iya naa le e ni Godwin gbe pada lọ sile lọdọ iya rẹ, nigba to si fi ede odi rẹ ṣalaye fun Mary ti i ṣe iya rẹ pe iya ọgọta ọdun naa le oun jade ninu ọgba wọn, inu bi iya rẹ naa, n lo ba ni ki Godwin niṣo nibẹ, o ni iya naa yoo ṣalaye idi to fi n le ọmọ oun jade ninu ọgba ile wọn.

Bi wọn ṣe n lọ ni ọmọ odi yii ti mu ẹkufọ igo kan sapo rẹ lati fi ba iya agbalagba naa ja, bi wọn si ti debẹ ti iya rẹ n ba iya ja pe ki lo le ọmọ oun jade fun, niṣe ni Godwin fa igo to ti tọju sapo yọ, o si fi gun iya naa lọrun.

Eyi lawọn to wa nitosi ṣe fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa teṣan Ojodun Abiọdun leti, SP Eyitayọ Akinluwade ti i ṣe DPO ibẹ si ran awọn ikọ rẹ lati lọọ mu iya atọmọ to daran naa wa.

Wọn sare gbe iya to gun nigo lọ sọsibitu, ṣugbọn dokita sọ pe obinrin naa ti ku. Wọn ti gbe oku naa lọ si mọṣuari, nitori wọn ni wọn yoo ṣe ayẹwo oku naa lati mọ ohun to fa iku rẹ gan-an.

Ni ti iya atọmọ arijagba, ẹsẹkẹsẹ ni wọn ti ko wọn lọ sẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ ipaniyan nipinlẹ Ogun, ibẹ ni wọn yoo wa ti wọn yoo fi gbe wọn lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply