Iya atọmọ ku somi nibi ti wọn ti n sa fawọn Boko Haram

Monisọla Saka

Ko sẹni to gbọ iṣẹlẹ iya atọmọ kan to n sa asala fẹmii wọn nitori awọn Boko Haram, ti wọn si ṣe bẹẹ ko somi.

O kere tan, ọgbọn eeyan, ti pupọ ninu wọn jẹ obinrin atawọn ọmọde ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn ni wọn ti pade iku lẹsẹ-o-gbeji l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lasiko ti ọkọ oju omi meji ti wọn wa ninu ẹ doju de.

Awọn olugbe ilu Birnin Wajje, lagbegbe Bukkuyum, nipinlẹ Zamfara, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ lawọn agbesunmọmi ọhun ya wọ abule wọn.

Birnin Wajje jẹ ilu ti omi yi i ka jinna ni iwọn kilomita meji si olu ijọba ibilẹ wọn to wa ni Bukkuyum, ko si ṣee ṣe feeyan lati jade kuro ninu ilu naa lai wọ ọkọ oju omi.

Lasiko tawọn eeyan ọhun n palẹmọ lati kirun lawọn agbebọn naa ya wọnu ilu wọn, wọn si n yinbọn leralera. Iro ibọn tawọn eeyan naa n gbọ lo ko jinnjinni ba wọn, onikaluku lo si n du ori ara ẹ lati ma ba ogun Boko Haram lọ.

Apa Iwọ Oorun ilu naa ni wọn ba wọle, ṣugbọn ko too di pe wọn wọ aarin ilu ni pupọ awọn araalu ti fẹsẹ fẹ ẹ, ọna Zauma, ilu kan to wa ni isọda omi ni wọn fori le, ko si si bi wọn ṣe le debẹ lai wọ ọkọ oju omi”.

Oluranlọwọ Gomina Bello Matawalle tipinlẹ Zamfara lori eto iroyin, Ibrahim Zauma, toun naa jẹ ọmọ apa ibẹ lo kọkọ sọrọ naa di mimọ lori ayelujara. O ni awọn ikọ mujẹmujẹ ti wọn ka wọn mọ’nu ilu lawọn eeyan ti pupọ ninu wọn jẹ obinrin atawọn ọmọde n sa fun ti ọkọ oju omi ti wọn n wọ sa lọ fi danu latari apọju ero ti ọkọ ko.

Lawali Sambo, to jẹ ọmọ ilu Zugu, ti ko fi bẹẹ jinna si ilu naa sọ pe awọn agbebọn naa ti gba iṣakoso Birnin Wajje bayii, gbogbo akitiyan awọn ikọ figilante adugbo lati koju wọn lo ja si pabo. Awọn Boko Haram yii bori wọn, wọn si ti fẹmi ọpọlọpọ wọn ṣofo.

Leave a Reply