Iya gbe miliọnu mẹta ti wọn fẹẹ fi ṣiṣẹ abẹ fọmọ ẹ sa lọ, lọmọ ọdun mẹta naa ba dagbere faye

Epe rabandẹ lawọn abiyamọ aye n gbe obinrin kan ti wọn n pe ni Iya Ada, ṣe bayii, afaimọ kawọn tọrun naa ma si ti maa bu epe to le jolẹ fun un pẹlu bi wọn ṣe lo ko miliọnu mẹta naira ti alaaanu kan san si akanti rẹ, lati fi sanwo itọju iṣẹ abẹ ọpọlọ ti wọn fẹẹ ṣe fun Ada, ọmọ ẹ, ọmọ ọdun mẹta, sa lọ.

Ori ẹka ayelujara Fesibuuku ni ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Nuhu Fulani Kwajafa, to jẹ alamoojuto fun ‘Global initiative for Peace, Love and Care, (GIPLC) ti kede pe loṣu to kọja yii, wọn gbe ọmọ ọdun mẹta kan, Ada, to ni iṣoro inu ọpọlọ wa sọdọ awọn fun iranlọwọ owo.  

 O ni alaaanu kan to fẹẹ gbe owo naa kalẹ sọ pe oun ko fọkan tan awọn ileeṣẹ to n ri si iṣoro ọmọniyan bayii, nitori wọn le da ori owo naa kọ ibomi-in, ki wọn ma na an fun alaisan teeyan tori ẹ ṣetọrẹ aanu.

 O lawọn tiẹ ni kẹni naa sanwo ọhun si apo ọsibitu ti wọn yoo ti ṣiṣẹ abẹ naa, ṣugbọn ọpọ nnkan ti wọn yoo nilo lo jẹ pe ita ni wọn yoo ti maa ra a, ọsibitu naa ko ni in.

Eyi lo fa a ti ẹlẹyinju aanu ọhun fi ni ki wọn kuku foun ni akanti iya ọmọ naa, koun sanwo sibẹ, ki iya si mọ bi yoo ṣe maa fi i ra ohun ti ọsibitu ba nilo, ati bi yoo ṣe sanwo itọju wọn fun wọn.

Afi bi owo ṣe wọ akanti Iya Ada tan ti wọn ko ri i lọsibitu mọ, to jẹ niṣe lo yọnda ọmọ rẹ ti jẹjẹrẹ ọpọlọ n ṣe naa sibẹ, to si lọ raurau.

Ọjo Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, ọsun kẹrin yii, ni ọmọdebinrin naa jade laye, nigba ti wọn ko rowo tọju ẹ nileewosan, ti ohun to n ṣe e si ju ẹmi rẹ lọ. Latigba naa lawọn eeyan ti n fepe ranṣẹ si Iya Ada nibi yoowu ko wa, wọn ni yoo jiya ohun to ṣe yii laye, yoo tun jẹ ẹ lajule ọrun paapaa.

 

 

Leave a Reply