Iya Gebu gbe ọmọ ọsẹ mẹta silẹ fọkọ ẹ, lo ba sa lọ l’Aparadija

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gabriel Ayọmide Ojo ni baba rẹ sọ ọ nigba ti wọn bi i lọdun mẹrin sẹyin, iyẹn ọmọkunrin kekere ti ẹ n wo aworan rẹ yii. Ṣugbọn Gebu lawọn eeyan n pe e laduugbo wọn l’Aparadija.

O gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta, nitori ohun meji kọ, nitori pe ọsẹ mẹta pere lo wa ti iya rẹ ti gbe e silẹ fun baba ẹ, to sa lọ bamubamu.

Kọlawọle Ojo ni baba rẹ n jẹ, Ruth lorukọ iya to bi i. Alaye ti baba ti ẹ n wo yii ṣe f’ALAROYE ni pe Iya to bi Ruth lo waa mu un kuro nile oun nigba ti ọmọ to bi foun ṣẹṣẹ pe ọmọ ọsẹ mẹta pere.

O loun lọọ wa ohun ti iyawo oun yoo jẹ lọjọ naa ni, koun too de loun ko ba a nile mọ pẹlu iya rẹ to waa wo o koun too jade nile. O ni Gebu ti wọn faṣọ we lori bẹẹdi nikan loun ba nibẹ, loun ba bẹrẹ si i wa iyawo oun ati iya rẹ kiri.

Baba Gebu sọ pe, ‘‘Mo wa wọn dele wọn, mi o ba wọn, wọn ti sa lọ. Mo daamu titi, mi o gburoo wọn mọ titi doni, emi ni mo n da tọju ọmọ yii, nitori mi o niyaa ati baba mọ. Ọdọ ẹgbọn mi ti mi o ba dẹ tun mu un lọ ko ṣee ṣe, nitori ile tiwọn naa ti kun’’

Akọroyin wa beere idi ẹ ti iya iyawo yoo fi waa mu ọmọ rẹ nile ọkọ, ti wọn si yọnda ọmọ ikoko bẹẹ fun baba rẹ lai wẹyin wo o mọ. Ohun to fi da wa lohun ni pe

‘‘Iya ẹ ko fẹ ko fẹ mi latilẹ. Iṣẹ awọn to n gbẹ sọkawee, gọta, fandeṣan ati bẹẹ bẹẹ lọ ni mo n ṣe. Iya iyawo mi loun ko nifẹẹ si iṣẹ naa nitori mi o le ri ṣe nibẹ, oun ko si le fọmọ fẹni ti ko ni nnkan kan.

‘‘Ọmọ ẹ ti lọkọ kan tẹlẹ ko too fẹmi, Hausa lọkunrin yẹn, iyawo mi bimọ kan fun un, ọmọkunrin lo bi fun Hausa yẹn naa. Iya ẹ naa lo lọọ mu un kuro nibẹ, ṣugbọn wọn ko fọmọ silẹ fun Mọla, wọn gbe ọmọ wọn lọ. Ọmọ temi ni wọn fi silẹ ti wọn kuro laduugbo fun mi.

‘‘Ọmọ yii maa pe ọdun mẹrin nipari ọdun yii, ko lọ sileewe, nitori mi o rowo ran an lọ. Lẹsinni ti wọn ti n san fifti Naira lojumọ ni mo n mu un lọ tẹlẹ, nigba ti Koro dẹ ti de lawọn iyẹn ti kogba wọle, ko lọ sibi kankan mọ bayii.

‘‘Ko rọ mi lọrun lati maa tọju ẹ, nitori mi o ki i riṣẹ ṣe deede. Bi mo fẹẹ lọọ tọ lasan, a jọ n lọ ni, nigba ti ko sẹni ti mo fẹẹ fi i silẹ fun. Bi mo ṣe n lọọ gbẹ koto kiri naa ni mo n mu un lọ.

‘‘Mo n bẹ awọn ọmọ Naijiria ki wọn ṣaanu mi lati tọju ọmọ yii. Awọn eeyan ti ju taya si mi lọrun ri ni Sango, wọn ni mo ji i gbe ni, abi bawo ni mo ṣe n gbe ọmọ kekere bẹẹ kiri lai si iya rẹ nibẹ.

‘‘Mo n fẹ iranlọwọ lati le mu un lọ sileewe, to ba n wa nibẹ, emi naa aa raaye ṣe daadaa. Mi o lowo lọwọ ti mo le fi fẹyawo mi-in to le ba mi tọju ẹ, atijẹ-atimu gan-an nira fun mi. Kawọn eeyan jọwọ, ran mi lọwọ, kọmọ mi kawe bi emi o tiẹ ka’’

ALAROYE ba Gebu naa sọrọ, ọmọ to kẹtan naa gbo lohun bii ọjẹ, ọrọ da lẹnu rẹ ṣaka, bo tilẹ jẹ pe ai ri itọju jẹ ko kere pupọ si ọjọ ori rẹ, niṣe lo da bii ọmọ ọdun meji pere. A beere pe nibo niya rẹ wa, o ni iya oun ti lọ. Gbogbo bawọn eeyan ṣe n kọja lọ lọmọ yii n ki wọn, bẹẹ lawọn iyẹn naa n sa a, ti wọn ki i bii pe agbalagba ẹgbẹ wọn ni.

Nigba ta a beere pe ṣe ki i ṣe ai ri itọju to naa lo sọ ẹsẹ rẹ di kẹrẹbutu bẹẹ, obinrin kan to n ṣe bii iya fun un (Ọmọ yii maa n duro lọdọ rẹ nigba mi-in ti baba rẹ ba wa jijẹ mimu lọ), lo dahun pe aanu Ọlọrun gan-an lo jẹ ko dide rin. O ni Gebu ko rin titi to fi pe ọmọ ọdun mẹta, nigba to si jaja dide ti ẹsẹ rẹ ṣe kẹrẹbutu, ẹru n dupẹ lawọn fi ọrọ naa ṣe, ko kuku sowo ti wọn yoo fi lọọ ba a tun ẹsẹ ṣe lọsibitu, ọmọ to jẹ bo ṣe ti dagba to yii, wọn ko ti i dako rẹ, atọtọ lo n gbe kiri titi dọla.

Koda, baba rẹ ko ni i foonu ni ka wi gẹgẹ bi obinrin naa ṣe wi (Baba Gebu funra ẹ naa si sọ bẹẹ), nitori batiri ko jẹ ki foonu to n lo gbadun. Ọpọ igba ti akọroyin wa n pe e ko too lọ sile rẹ ni foonu naa ki i wọle, ti obinrin to n ba a gba Gebu sọdọ la bẹrẹ si i pe ko too di pe a dele wọn.

Inu ile ti won n gbe ree

Bi ẹnikẹni ba fẹẹ ṣaanu Gebu lati lọ sileewe, tabi to fẹẹ ran baba rẹ lọwọ lati maa rọwọ mu lọ sẹnu, ko si tun le maa tọju ọmọ naa si i, eyi ni nọmba asunwọn ti tọhun le fowo si: 0169538111, Oluwarotimi Ọladele Ọlatokunbọ , GT Bank.

Eni to ba si fẹẹ pe e lati ridi ododo le pe sori nọmba rẹ yii 09098380761 tabi 08032054735.

Leave a Reply