‘Iya kankan ko le jẹ Sunday Igboho lọdọ wa, emi naa ba Yoruba tan nidii iya’  

Jọkẹ Amọri

Pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe n lọ, o ti han pe didun lọsan yoo so fun ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho. Ireti si wa pe gbogbo ilakaka ijọba orileede Naijiria lati gbe ajijagbara naa pada si Naijiria ko ni i so eso rere.

Eyi foju han pẹlu aṣiri kan to ṣẹṣẹ tu si ALAROYE lọwọ lori bi Igboho ṣe wa ni ilẹ Benin. Ohun ti a gbọ ni pe iṣẹ ti n lọ, wọn si ti n ṣe iwe igbanilaaye lati gbe ilu ẹni (Benin) nitori wahala ti wọn n pe ni (asylum). Ẹni to yọ ọrọ yii sọ fun wa sọ pe wọn ko ni i pẹẹ pari iṣẹ lori eleyii.

Iroyin mi-in ti ALAROYE tun gbọ latọdọ awọn to mọ bo ṣe n lọ lori ọrọ Sunday Igboho ti wọn sọ fun wa ni pe Olori orileede Olominira Benin, Aarẹ Patrice Talon, ti fi da gbogbo awọn ti wọn n ṣabẹwo si ọkunrin naa lori ọrọ Sunday Igboho loju pe ki wọn fọkan balẹ, o ni ko si nnkan ti yoo ṣe ajijagbara naa lọdọ awọn.

Talon ni apa kan ẹya Yoruba loun naa nitori oun tan mọ ilẹ Yoruba nidii iya. Iyẹn ni pe apa kan Yoruba loun, oun ko si le fiya jẹ, tabi ki oun gba ẹnikẹni laaye lati fiya jẹ ẹni to jẹ iran oun.

Ẹni to ba wa sọrọ naa sọ fun akọroyin wa pe ilẹ Benin ko fẹ ija Naijiria ni wọn fi n gbe igbesẹ ti wọn n gbe lori Naijiria. O ni ti orileede naa ko ba fọgbọn ṣe e, gbogbo ọna ni ijọba Naijiria le gba lati fiya jẹ wọn nitori gbogbo ọna ni ilẹ wa fi lagbara ju wọn lọ.

Ẹru eleyii n ba ijọba Benin gẹgẹ bi ẹni naa ti sọ fun wa. Bẹẹ ni wọn si mọ pe o lodi sofin lati fa Sunday Igboho le ilẹ Naijiria lọwọ. Nitori pe aarin arẹwa meji lawọn eeyan naa wa ni wọn fi n rọra ṣe.

Ẹni yii sọ fun wa pẹlu idaniloju pe Sunday Igboho ko ni i pẹẹ jade kuro nilẹ Benin ni kete ti wọn ba ti pari iwe rẹ, ṣugbọn ko sẹni to maa mọgba to maa kuro nibẹ, ko maa baa la ariwo ati wahala lọ. O ni yoo ti debi to n lọ ki awọn eeyan too mọ.

O fi kun un pe iṣẹ kekere kọ ni awọn agbaagba Yoruba kan ṣe lori ọrọ yii, bẹẹ lo ni awọn ọba Yoruba to wa nilẹ Benin paapaa ṣagbara lori ọrọ naa.

O waa ni pẹlu ileri ti olori ilẹ Benin ṣe, idaniloju wa pe wọn ko ni i gbe Igboho pada si Naijiria.

Nigba ti akọroyin wa beere lọwọ rẹ pe pẹlu idajọ ile-ẹjọ kan to dajọ niluu Ibadan lọsẹ to kọja pe ki wọn ma halẹ mọ Igboho, ki wọn ma gbe e, ki wọn si ma sọ pe awọn maa fiya kankan jẹ ẹ, ṣe ọkunrin naa le pada si ilẹ wa.

Ọkunrin naa rẹrin-in, o ni a n sọrọ bii pe a ko mọ pe ijọba Naijiria ki i bọwọ fun ofin. O ni wọn le ji lọjọ kan ki wọn ka ẹsun mi-in si i lẹsẹ ti wọn yoo fi gbe e. Wọn si le ji i gbe paapaa to jẹ pe nigba ta a ba maa fi gburoo rẹ, atimọlẹ awọn ọtẹlẹmuyẹ la ti maa gbọ ọ. O ni gbogbo eleyii ni ijọba ilẹ Benin n sa fun ti wọn fi n ṣe gbogbo ohun ti wọn n ṣe lori ọrọ naa.

Leave a Reply