Iya mi lo maa n ro mi lagbara nigbakuugba ta a ba fẹẹ lọọ digunjale- Timileyin

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kayeefi nla lo jọ loju awọn to wa nibi ti ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹtala kan, Timilẹyin Fẹmi, ti n ka boroboro lori ipa ti oun atawọn ikọ rẹ n ko lori ọkan-o-jọkan idigunjale to n waye niluu Akurẹ ati agbegbe rẹ.
Ninu alaye ti Timilẹyin, ẹni tawọn ẹgbẹ rẹ mọ si Anini, ṣe fawọn oniroyin lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lọfiisi ẹṣọ Amọtẹkun to wa ni Alagbaka, l’Akurẹ, lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a wa yii, ni oun ko le ka iye awọn eeyan ti awọn ti ja lole laarin igba ti oun darapọ mọ ikọ adigunjale ẹlẹni mẹrin ọhun.
O ni gbogbo igba tawọn ba ti n lọọ digunjale ni iya oun maa n ro oun lagbara pẹlu oogun abẹnugọngọ kọwọ awọn ọlọpaa tabi Amọtẹkun ma baa tẹ oun.
Ni kete to darapọ mọ ikọ awọn adigunjale naa lo ni wọn ti fun oun lorukọ inagijẹ ti i ṣe Anini, orukọ yii lo ni oun si n jẹ nigbakuugba ti awọn ba ti wa lẹnu isẹ ole jija.
Anini ni ibọn ilewọ lawọn n lo lati fi jale nitori ọjọ ori awọn, ati pe awọn to n ko nnkan ija fun awọn ki i fun awọn ni ibọn nla.
Timilẹyin ni ori aja ile babalawo awọn iyẹn, Ọdẹyẹmi Ayọdele, lawọn maa n ko nnkan ija naa pamọ si, ati pe ọkunrin ẹni ogun ọdun ọhun gan-an lawọn maa n jabọ iṣẹ idigunjale ti awọn n ṣe fun.
Babalawo ọhun lo ni ki i fawọn ju ẹgbẹrun meji Naira pere lọ fun ọkọọkan isẹ tawọn n ṣe fun un.

Ọmọ ọdun mẹrindinlogun pere ni olori awọn adigunjale ọhun, Ojo Sunday lo porukọ ara rẹ, ṣugbọn o da bii ẹni pe iṣẹ ibi ọwọ rẹ lo jẹ kawọn eeyan ilu Ijarẹ, nibi ti wọn fi ṣe ibujokoo wọn fun un ni inagijẹ Oyenusi to n jẹ.
Ninu ọrọ diẹ to ba awọn akọroyin sọ, o ni ọkada lawọn fi n digunjale, ati pe nibi kan tawọn ti lọọ digunjale laipẹ yii ni wọn ti lu oun ni alubami.
A gbiyanju lati fọrọ wa Abilekọ Iyabọ Fẹmi to jẹ iya Timilẹyin lẹnu wo, obinrin naa ṣẹ kanlẹ lori ẹsun ti ọmọ rẹ fi kan an pe oun lo maa n dira oogun foun nigba tawọn ba ti n lọ soko ole.
Iyabọ ni oun gbiyanju ati mu ọmọ oun lọ si ṣọọsi lẹyin tọwọ ti kọkọ tẹ ẹ lọdun to kọja lori ẹsun yii kan naa.
O ni ṣọọsi ni wọn ti foun lọsẹ iwẹ kan, eyi ti oun lọọ fi wẹ ẹ leti odo nigba naa ki oju rẹ le ṣi kuro lara ole jija.
O ni loootọ ni ko fi bẹẹ jale mọ lẹyin to wẹ iwẹ odo tan, ṣugbọn kete to tun foju kan Sunday ọga rẹ lo tun bẹrẹ lakọtun.
Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni Timilẹyin ko ti i ju bii ọmọ ọdun mejila pere lọ nigba tọwọ awọn kọkọ tẹ ẹ lọdun to kọja lori ẹsun idigunjale.
O ni ọjọ ori rẹ to kere lawọn wo mọ ọn lara ti awọn ko fi ba a ṣẹjọ lọ titi nigba naa, O ni ohun tawọn ro niyi ti awọn fi kilọ fun un, ti awọn si fa a le iya rẹ lọwọ lati tete lọọ mojuto o.
O ni ohun ti awọn fidi rẹ mulẹ lẹyin tọwọ pada tẹ ọmọ to ti kekere yan iṣẹ ọdaran laayo ọhun ni pe iya rẹ gan-an lo n ṣatilẹyin fun un, to si maa n dira oogun gidi fun un lasiko ti wọn ba ti n lọ ṣiṣẹ ibi wọn.

Adelẹyẹ ni ohun ti wọn ni iya rẹ maa n sọ ni pe ọmọkunrin ọhun nikan loun bi, oun ko si ni i laju oun silẹ ki wọn yinbọn pa a mọ oun lọwọ.
Adelẹyẹ ni bakan naa lawọn tun fi panpẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ogun ọdun, Ọdẹyẹmi Ayoade, (Osunbor) to jẹ baba isalẹ ati babalawo wọn pẹlu iya rẹ, Abilekọ Kẹhinde Ayọmide.
Gbogbo awọn tọwọ tẹ ọhun lo ni awọn yoo ko lọ sile-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ wọn.

Leave a Reply