Iya mi ni Babajide Sanwo-Olu ni baba mi, ti ko ba da wọn loju ki wọn jẹ ka ṣe ayẹwo ẹjẹ – Emmanuel

Faith Adebọla, Eko

Ẹjọ nla kan ti wa ni nile-ẹjọ giga ipinlẹ Delta, to fikalẹ siluu Effunrun. Ọdọmọkunrin kan, Emmanuel Moses Sanwo-Olu, lo pẹjọ naa. Gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ni wọn pe lẹjọ. Emmanuel ni Sanwo-Olu ni baba oun, oun si fẹ kile-ẹjọ ba oun fidi ẹ mulẹ fun gomina pe ọmọ bibi inu ẹ loun i ṣe.

Ninu iwe ipẹjọ jan-an-ran jan-an-ran kan ti wọn kọ ni ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, eyi ti nọmba rẹ jẹ EHC/148/2022, olupẹjọ naa, nipasẹ agbẹjọro rẹ, Ọgbeni J. O. Aikpokpo-Martins, ṣalaye pe mama oun, Abilekọ Grace Moses, sọ foun pe Babajide Sanwo-Olu loun bi oun fun. O sọ pe oun pade gomina Eko yii labule kan ti wọn n pe ni Oleri, niluu Warri,  lọdun 1994, lasiko ti ọkunrin naa n ṣiṣẹ nileeṣẹ kan niluu ọhun. Wọn jọ sọrọ ifẹ, wọn si jọ laṣepọ laimọye igba laarin ọdun 1994 naa si ọdun 1995.

Wọn lọdun 1994 ni Grace loyun latari ajọṣepọ oun ati Gomina Sanwo-Olu, ko si fọrọ oyun naa di i leti, bẹẹ ni Sanwo-Olu ko jampata nigba to gbọ, ṣugbọn ko pẹ lẹyin naa ni wọn ko ri Sanwo-Olu mọ, o kuro lagbegbe naa, obinrin yii ko si mọbi to wa fun igba pipẹ.

Lọjọ ikunlẹ, Grace sọ layọ, o bi ọmọkunrin, o si sọ ọmọ naa lorukọ Emmanuel Moses, tori Moses lorukọ idile obinrin naa.

Emmanuel ni mama oun lo da nikan tọ oun dagba, ninu ipọnju ati itiju ni obinrin naa n gbọ bukaata oun. Nigba to ya, lẹyin toun ti wọ ileewe pamari, oun beere lọwọ iya oun nipa baba oun, gbogbo ohun to fi fesi foun ko ju pe ọkunrin kan bayii ti wọn n pe ni Jide Sanwo-Olu loun bi oun fun, ati pe agbegbe Ijẹbu-Ode ati Ẹpẹ lo loun ti wa, ko si dagbere foun to fi ja oun ju silẹ toyun-toyun, toun ko si ri i mọ.

O ni mama oun sọ foun pe lara nnkan toun ranti nipa baba oun yii ni pe ọlọwọ-osi ni, ko si fẹran lati da irungbọn si rara, o maa n fa agbọn rẹ dan ni, ati pe ọmọluabi eeyan ni, o niwa jẹẹjẹ, o maa n bọwọ fun-unyan, wẹrẹwẹrẹ lo si maa n sọrọ, o maa n bikita.

Emmanuel ni ọrẹ oun kan lo pe oun sakiyesi Sanwo-Olu nigba ti wọn ṣafihan rẹ lori tẹlifiṣan, nibi to ti n ṣi awọn iṣẹ ode kan, oun ri i pe awọn jọra, ati pe ọwọ osi naa ni Sanwo-Olu n lo, afijọ kan naa lawọn ni.

O loun wo fidio naa lawotunwo, loun ba lọ sori ẹrọ instagiraamu Sanwo-Olu, oun tẹ awọn oriṣiiriṣii fọto jade nibẹ, oun si ko wọn lọọ ba mama oun boya o maa le da ẹni to bi oun fun mọ, taarata ni mama naa fa fọto Babajide Sanwo-Olu jade pe oun ni ọkunrin to fun oun loyun niyẹn, bo tilẹ jẹ pe mama naa ko mọ pe o ti di gomina rara.

O loun tun ṣafihan fidio ti Sanwo-Olu wa ninu rẹ fun mama oun, obinrin naa si tubọ fidi ẹ mulẹ pe dajudaju, baba oun niyẹn, ẹni toun ati ẹ jọ ṣere ifẹ lọdun 1994 si 1995 niyẹn.

O ni atigba naa loun ti n ṣan gbogbo ọna lati ri Sanwo-Olu, ṣugbọn gbogbo igbiyanju oun lo ja si pabo latari bi awọn ẹṣọ alaabo ati ipo gomina to wa ṣe n gbegi dina foun, eyi lo jẹ koun kọri sile-ẹjọ, ki wọn le beere ẹtọ oun foun.

Lara ẹbẹ ti olupẹjọ yii fi siwaju ile-ẹjọ ni pe ki wọn ba oun kede pe olujẹjọ naa ni baba oun, pe oun ni Abilekọ Grace Moses, ti i ṣe iya oun, bi i fun.

O tun rọ ile-ẹjọ pe ki wọn paṣẹ fun olujẹjọ naa lati mu oun bii ọmọ, ko si maa ṣetọju oun, ki oun le lanfaani si gbogbo ẹtọ to ba yẹ ki ọmọ ri latọdọ baba rẹ, tori baba oun ni Sanwo-Olu.

Bakan naa lo ni oun ko lodi si ṣiṣe ayẹwo ẹjẹ awọn mejeeji, to ba pọn dandan lati ṣe bẹẹ, ki wọn le fidi okodoro otitọ mulẹ.

Leave a Reply