Iya n jẹ wa pupọ lorileede yii, ẹ jẹ ka gbogun ti iwa ijẹgaba awọn Fulani-Ayọ Adebanjọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adari ẹgbẹ Afẹnifẹre lorileede yii, Oloye Ayọ Adebanjọ, ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gbiyanju lati yi ọrọ to n lọ lọwọ lorileede yii pada rara nipasẹ ibanilorukọ jẹ, ṣugbọn ki wọn sọ fun ijọba lati gbe igbesẹ to tọ.

Oloye Adebanjọ, ẹni to sọrọ naa nibi eto isinku ti wọn ṣe fun alukoro ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin, eyi to waye niluu Moro, nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ṣalaye pe ko si ẹnikankan to nifẹẹ pe ki orileede yii pin yẹlẹyẹlẹ, bi ko ṣe ki atunto ba iṣakoso rẹ.

O ni ko si bi awọn eeyan bii Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu ko ṣe ni maa ni awọn ọmọlẹyin fun ijijagbara wọn kaakiri niwọn igba ti ijọba apapọ ba kuna lati ṣe ohun to tọ.

Gẹgẹ bi baba naa ṣe wi, “O ṣe mi laaanu pe mo n sọrọ nibi isinku ọmọ-ọmọ mi. Mo gboṣuba fun Yinka Odumakin, o ṣiṣẹ takuntakun fun ẹgbẹ Afẹnifẹre lai beere ohunkohun. Yinka ti lọ, ṣugbọn Afẹnifẹre yoo wa pẹlu awọn ọmọ rẹ.

“Olotitọ eeyan ti ko bẹru ẹnikẹni ni Yinka. O maa n wo awọn alaṣẹ loju lati ba wọn sọ ohun to n jẹ otitọ ọrọ. Ẹ jẹ ka gbogun ti iwa ijẹgaba awọn Fulani, ka sọ otitọ ọrọ. Iya n jẹ wa pupọ lorileede yii, atunto gbọdọ ba orileede yii ti a ko ba fẹẹ fọ si wẹwẹ.

“Awa Afẹnifẹre atawọn to n beere fun atunto Naijiria ni ọrẹ ti Aarẹ Mohammadu Buhari ni. A ko ni i gba ki ẹnikẹni dabaru afojusun wa. A ko sọ pe ki gbogbo awọn Fulani maa lọ, awọn darandaran ti wọn n fipa ba awọn obinrin wa sun, ti wọn n wọnu oko wa, ti wọn n pa awọn eeyan wa, la sọ pe ki wọn ma a lọ.

“Ijọba gbọdọ fi panpẹ ofin mu wọn, ẹya mi-in ti wọn ba tun ti kofiri iru ẹ, ki wọn le wọn danu. A ti ja fitafita fun ilọsiwaju orileede yii, ki i ṣe ki awọn ẹya kan maa jẹ gaba le wa lori, a ko fẹ iyanjẹ rara.

“Ọna kan ṣoṣo ti awa ẹgbẹ Afenifẹre le gba bu ọla fun Yinka ni ka tẹ siwaju ninu iṣẹ to n ṣe ati ohun gbogbo to n ja fun lai duro, lai wẹyin ati lai yẹsẹ”

Leave a Reply