Iya n run nimu awọn ileepo ti ko ba ta epo faraalu-Ogundoyin

Ọlawale Ajao, Ibadan

O ṣee ṣe ki ijọba fiya jẹ awọn ileepo ti wọn ko ba ta bẹtiroolu fawọn araalu. Iyẹn bi wọn ba tẹle imọran ti Kọmiṣanna fọrọ iṣẹ ode ati eto irinna nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Dauda Kẹhinde Ogundoyin, gba awọn DPP, iyẹn ajọ to n ri sì ìdíyelé epo bẹtiroolu nilẹ yii lati wa nnkan ṣe si ọrọ awọn ileepo ti wọn kọ láti ta epo.

Nigba to n kopa lori eto ori redio aladaani kan nigboro Ibadan laaarọ ọjọ Ajé, Mọnde, ọsẹ yii, Ọjọgbọn Ogundoyin sọ pe ijọba ko lọwọ si ọwọngogo epo bẹtiroolu tó wà níta bayii, awọn to n ta epo ni wọn kàn mọ-ọn-mọ tilẹkun mọ ọja wọn ti wọn si ṣe bẹẹ ko inira ba gbogbo araalu.

 

Lati ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lepo bẹtiroolu ti dọwọngogo pẹlu bi ọpọlọpọ ileepo ṣe kọ lati  taja fẹnikẹni nitori ti wọn ro pe epo maa gbowo lori latọdọ ijọba apapọ.

Ero rẹpẹtẹ ati ọkẹ aimọye ohun irinṣẹ lo n to lati ra epo lawọn ileepo kọọkan ti wọn ba jaja ṣi ileetaja wọn, ti awọn eeyan si fẹẹ le maa lura wọn ki wọn too le ri epo ra titi dọsan ọjọ Mọnde ta a pari akojọ iroyin yii.

Eyi lo fa a to jẹ pe ba a ṣe n wi yii, ohun gbogbo lo ti gbowo lori bayii pẹlu bi awọn ontaja ṣe n pariwo pe owo ti awọn fi wọ mọto lọọ raja ati eyi ti awọn fi ko o ki i ṣe kekere.

Leave a Reply